< Song of Solomon 1 >

1 Orin, àwọn orin tí í ṣe orin Solomoni. 2 Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ. 3 Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra. Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ. 4 Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀. Ọ̀rẹ́ Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ; a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ. Olólùfẹ́ Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́! 5 Èmi dúdú mo sì ní ẹwà. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari, bí aṣọ títa ti Solomoni. 6 Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú, nítorí oòrùn mú mi dúdú, ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà; ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú. 7 Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́, níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ. Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán, kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. 8 Bí ìwọ kò bá mọ̀, ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin. Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ, kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ. Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn. 9 Olùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Farao. 10 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́, ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀. 11 A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ, a ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀. 12 Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀, òróró ìkunra mi tú òórùn jáde. 13 Ìdì òjìá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi, òun ó sinmi lé àárín ọmú mi. 14 Bí ìdì ìtànná Henina ni olùfẹ́ mi rí sí mi láti inú ọgbà àjàrà ti En-Gedi. 15 Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi! Háà, báwo ni o ṣe lẹ́wà tó! Ìwọ ní ojú ẹyẹlé. 16 Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi! Háà, báwo ni o ṣe wu ni! Ibùsùn wa ní ìtura. 17 Ìtànṣán ilé wa jẹ́ ti igi kedari ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi firi.

< Song of Solomon 1 >