< Psalms 96 >

1 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa, ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé. 2 Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀ ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́. 3 Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn. 4 Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí; òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ. 5 Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run. 6 Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀ agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀. 7 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn, ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa. 8 Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un; ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀. 9 Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀; ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé. 10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba.” A fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí; ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn. 11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo jẹ́ kí pápá òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. 12 Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀; nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀. 13 Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa, nítorí tí ó ń bọ̀ wá, ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.

< Psalms 96 >