< Psalms 87 >

1 Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin. Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́; 2 Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ. 3 Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀, ìlú Ọlọ́run, 4 “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi, yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’” 5 Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ, “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀, àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.” 6 Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀: “Eléyìí ni a bí ní Sioni.” 7 Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu ohun èlò orin yóò wí pé, “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”

< Psalms 87 >