< Psalms 86 >

1 Àdúrà ti Dafidi. Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn, nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní. 2 Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ: ìwọ ni Ọlọ́run mi, gbà ìránṣẹ́ rẹ là tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ. 3 Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́. 4 Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ, Olúwa, ni mo gbé ọkàn mí sókè sí. 5 Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa, ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́. 6 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa; tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú. 7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́, nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn. 8 Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa: kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ. 9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá yóò wá láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa; wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀. 10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ni Ọlọ́run. 11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa, èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ; fún mi ní ọkàn tí kì í yapa, kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ. 12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé. 13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi; ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú. (Sheol h7585) 14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run; àti ìjọ àwọn alágbára ń wá ọkàn mi kiri, wọn kò sì fi ọ́ pè. 15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere, Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́. 16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi; fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là. 17 Fi àmì hàn mí fún rere, kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri, kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa ni ó ti tù mí nínú.

< Psalms 86 >