< Psalms 83 >

1 Orin. Saamu ti Asafu. Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́; má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́. 2 Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ, bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè. 3 Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ; wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́. 4 Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè, kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.” 5 Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan; wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ 6 Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli, ti Moabu àti ti Hagari 7 Gebali, Ammoni àti Amaleki, Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire. 8 Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. (Sela) 9 Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midiani bí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni, 10 ẹni tí ó ṣègbé ní Endori tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀. 11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu, àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna, 12 tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní àní pápá oko tútù Ọlọ́run.” 13 Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà, bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́. 14 Bí iná ti í jó igbó, àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná, 15 bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ. 16 Fi ìtìjú kún ojú wọn, kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa. 17 Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn 18 jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa: pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.

< Psalms 83 >