< Psalms 80 >

1 Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì Ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu. Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli; ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran. Ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde 2 níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase. Ru agbára rẹ̀ sókè; wá fún ìgbàlà wa. 3 Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run; jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí a bá à lè gbà wá là. 4 Olúwa Ọlọ́run alágbára, ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ? 5 Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 6 Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá. 7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára; jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa, kí a ba à lè gbà wá là. 8 Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti; ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín. 9 Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un, ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀ ó sì kún ilẹ̀ náà. 10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run. 11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun, ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì. 12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀ tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀? 13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́ àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run. 14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára! Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó! Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò, 15 gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn, àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ. 16 A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún; ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé. 17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ. 18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ; mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ. 19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára; kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí á ba à lè gbà wá là.

< Psalms 80 >