< Psalms 76 >

1 Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin. Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run; orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli 2 Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu, ibùgbé rẹ̀ ni Sioni. 3 Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà, asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. (Sela) 4 Ìwọ ni ògo àti ọlá, ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ. 5 A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn; kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè. 6 Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu, àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀. 7 Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù. Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú? 8 Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run, ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́, 9 nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run, bá dìde láti ṣe ìdájọ́, láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. (Sela) 10 Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ, ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè. 11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ; kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù. 12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò; àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.

< Psalms 76 >