< Psalms 61 >

1 Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi. Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run; tẹ́tí sí àdúrà mi. 2 Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́, mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀; mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ. 3 Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi, ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá. 4 Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ. 5 Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run; Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ. 6 Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn, ọdún rẹ̀ fún ìrandíran. 7 Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé; pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ. 8 Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.

< Psalms 61 >