< Psalms 47 >

1 Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀. 2 Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó ọba ńlá lórí gbogbo ayé. 3 Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa 4 Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa, ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa. 5 Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀, Olúwa ti òun ti ariwo ìpè. 6 Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn. Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn! 7 Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé, ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu! 8 Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí; Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀. 9 Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni, òun ni ó ga jùlọ.

< Psalms 47 >