< Psalms 138 >

1 Ti Dafidi. Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo; níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ. 2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀ èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ; nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ. 3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn, ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi. 4 Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́, Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. 5 Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa; nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa. 6 Bí Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré. 7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè; ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí. 8 Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé; Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé; má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.

< Psalms 138 >