< Psalms 136 >

1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun; 2 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run: 3 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, 4 Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá; 5 Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; 6 Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi; 7 Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá; 8 Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán; 9 Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; 10 Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn; 11 Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn; 12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà; 13 Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà; 14 Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀ 15 Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa; 16 Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já 17 Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá; 18 Ó sì pa àwọn ọba olókìkí 19 Sihoni, ọba àwọn ará Amori 20 Àti Ogu, ọba Baṣani; 21 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, 22 Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀, 23 Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa; 24 Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa; 25 Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo 26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;

< Psalms 136 >