< Psalms 126 >

1 Orin fún ìgòkè. Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà, àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá. 2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín, àti ahọ́n wa kọ orin; nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé, Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn. 3 Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa; nítorí náà àwa ń yọ̀. 4 Olúwa mú ìkólọ wa padà, bí ìṣàn omi ní gúúsù. 5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka. 6 Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí rẹ̀.

< Psalms 126 >