< Psalms 123 >

1 Orin fún ìgòkè. Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí, ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run. 2 Kíyèsi, bí ojú àwọn ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn, àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa, títí yóò fi ṣàánú fún wa. 3 Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa; nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀. 4 Ọkàn wa kún púpọ̀ fún ẹ̀gàn àwọn onírera, àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.

< Psalms 123 >