< Psalms 121 >

1 Orin fún ìgòkè. Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì— níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá? 2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá, ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé. 3 Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀; ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé. 4 Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́, kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn. 5 Olúwa ni olùpamọ́ rẹ; Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ. 6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán tàbí òṣùpá ní ìgbà òru. 7 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo yóò pa ọkàn rẹ mọ́ 8 Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́ láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

< Psalms 121 >