< Psalms 120 >

1 Orin fún ìgòkè. Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi, ó sì dá mi lóhùn. 2 Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn. 3 Kí ni kí a fi fún ọ? Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn? 4 Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun, pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀. 5 Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki, nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari! 6 Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà. 7 Ènìyàn àlàáfíà ni mí; ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.

< Psalms 120 >