< Psalms 115 >

1 Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa, ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún, fún àánú àti òtítọ́ rẹ. 2 Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé, níbo ni Ọlọ́run wa wà. 3 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run: tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú. 4 Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni. 5 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀, wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran. 6 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀: wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn. 7 Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó, wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn. 8 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn. 9 Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn 10 Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn. 11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn. 12 Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli; yóò bùkún ilé Aaroni. 13 Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa, àti kékeré àti ńlá. 14 Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀. 15 Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé. 16 Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa: ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn. 17 Òkú kò lè yìn Olúwa, tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́. 18 Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. Ẹ yin Olúwa.

< Psalms 115 >