< Proverbs 6 >

1 Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ, bí ìwọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì ènìyàn, 2 bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté. 3 Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ níwọ̀n bí o ti kó ṣọ́wọ́ aládùúgbò rẹ: lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀; bẹ aládùúgbò rẹ dáradára. 4 Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́, tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá. 5 Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo èsúró kúrò lọ́wọ́ ọdẹ, bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ. 6 Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ; kíyèsi ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n! 7 Kò ní olùdarí, kò sí alábojútó tàbí ọba, 8 síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè. 9 Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ? Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ? 10 Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀. 11 Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà àti àìní bí adigunjalè. 12 Ènìyànkénìyàn àti ènìyàn búburú, tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri, 13 tí ó ń ṣẹ́jú pàkòpàkò, ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe, 14 tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀ ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀. 15 Nítorí náà ìdààmú yóò dé bá a ní ìṣẹ́jú akàn; yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe. 16 Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i, 17 Ojú ìgbéraga, ahọ́n tó ń parọ́ ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, 18 ọkàn tí ń pète ohun búburú, ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà, 19 ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan. 20 Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́ má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀. 21 Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ. 22 Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ; nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ; nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀. 23 Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí ni ọ̀nà sí ìyè. 24 Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú, kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì. 25 Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra. 26 Nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè obìnrin ni ènìyàn fi ń di oníṣù-àkàrà kan, ṣùgbọ́n àyà ènìyàn a máa wá ìyè rẹ̀ dáradára. 27 Ǹjẹ́ ọkùnrin ha le è gbé iná lé orí itan kí aṣọ rẹ̀ má sì jóná? 28 Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná? Kí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì má jóná? 29 Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya; kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láìjìyà. 30 Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á. 31 Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà. 32 Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè kò nírònú; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni. 33 Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀, ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé. 34 Nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè, kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san. 35 Kò nígbà nǹkan kan bí ohun ìtánràn; yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.

< Proverbs 6 >