< Proverbs 17 >

1 Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà. 2 Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ, yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ. 3 Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà, ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò. 4 Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi; òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú. 5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà. 6 Ọmọ ọmọ ni adé orí arúgbó, ògo àwọn ọmọ sì ni òbí jẹ. 7 Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aṣiwèrè, bẹ́ẹ̀ ni ètè èké kò yẹ ọmọ-aládé! 8 Òkúta iyebíye jẹ́ ẹ̀bùn ní ojú ẹni tí ó ni í, ibikíbi tí ó yí sí, á ṣe rere. 9 Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà. 10 Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyàn ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀. 11 Orí kunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe, ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i. 12 Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọ jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀. 13 Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ìre, ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé. 14 Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi; nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà. 15 Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, Olúwa kórìíra méjèèjì. 16 Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè, níwọ̀n bí kò ti ní èròǹgbà láti rí ọgbọ́n? 17 Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú. 18 Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra, ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀. 19 Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀; ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun. 20 Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú, ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu. 21 Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn, kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n. 22 Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi, ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ. 23 Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ láti yí ìdájọ́ po. 24 Olóye ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú, ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé. 25 Aṣiwèrè ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ. 26 Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀, tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn. 27 Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, ènìyàn olóye sì máa ń ní sùúrù. 28 Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọ́gbọ́n bí ó bá dákẹ́, àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.

< Proverbs 17 >