< Nehemiah 7 >

1 Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì ri àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Lefi. 2 Mo fún Hanani arákùnrin mi pẹ̀lú Hananiah olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jerusalẹmu, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòtítọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ. 3 Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ ṣí ìlẹ̀kùn Jerusalẹmu títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.” 4 Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́. 5 Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà. 6 Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó ní ìgbèkùn (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú u rẹ̀. 7 Wọ́n jọ rìn wá pẹ̀lú u Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordekai, Bilṣani, Misperi, Bigfai, Nehumu, àti Baanah). Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọkùnrin Israẹli, 8 àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án 9 Ṣefatia jẹ́ òjìdínnírinwó ó lé méjìlá 10 Arah jẹ́ ẹgbẹ̀tàléláàádọ́ta ó lé méjì 11 Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnlá ó lé méjìdínlógún 12 Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin 13 Sattu jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún 14 Sakkai jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin 15 Binnui jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́jọ 16 Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n 17 Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó dín méjìdínlọ́gọ́rin 18 Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méje 19 Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin 20 Adini jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé márùn-ún 21 Ateri (láti ipasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún 22 Haṣumu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́jọ 23 Besai jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́rin 24 Harifu jẹ́ méjìléláàádọ́fà 25 Gibeoni jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn. 26 Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu àti Netofa jẹ́ igba ó dín méjìlélógún 27 Anatoti jẹ́ méjìdínláàádóje 28 Beti-Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì 29 Kiriati-Jearimu, Kefira, àti Beeroti jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta 30 Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún 31 Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà 32 Beteli àti Ai jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà 33 Nebo mìíràn jẹ́ méjìléláàádọ́ta 34 Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta 35 Harimu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó 36 Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún. 37 Lodi, Hadidi, àti Ono jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé ọ̀kan 38 Senaa jẹ́ ẹgbàajì ó dín àádọ́rin. 39 Àwọn àlùfáà: àwọn ọmọ Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún dín lẹ́gbẹ̀rin ó dín méje 40 Immeri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì 41 Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta 42 Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún. 43 Àwọn ọmọ Lefi: àwọn ọmọ Jeṣua (láti ipasẹ̀ Kadmieli, láti ipasẹ̀ Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin. 44 Àwọn akọrin: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjìdínláàádọ́jọ. 45 Àwọn aṣọ́nà: àwọn ọmọ Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita, àti Ṣobai jẹ́ méjìdínlógóje. 46 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. Àwọn ọmọ Siha, Hasufa, Tabboati, 47 Kerosi, Sia, Padoni, 48 Lebana, Hagaba, Ṣalmai, 49 Hanani, Giddeli, Gahari, 50 Reaiah, Resini, Nekoda, 51 Gassamu, Ussa, Pasea, 52 Besai, Mehuni, Nefisimu, 53 Bakbu, Hakufa, Harhuri, 54 Basluti, Mehida, Harṣa, 55 Barkosi, Sisera, Tema, 56 Nesia, àti Hatifa. 57 Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni: àwọn ọmọ Sotai, Sofereti; Perida, 58 Jaala, Darkoni, Giddeli, 59 Ṣefatia, Hattili, Pokereti-Haṣṣebaimu, àti Amoni. 60 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ. 61 Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli. 62 Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì. 63 Lára àwọn àlùfáà ni: àwọn ọmọ Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè). 64 Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́. 65 Baálẹ̀ sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu yóò fi dé. 66 Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó, 67 yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀ta dín lẹ́gbàárin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta; wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún. 68 Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin, ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún; 69 ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún; kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin. 70 Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà. 71 Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ogún ẹgbẹ̀rún dariki wúrà àti ẹgbọ̀kànlá mina fàdákà. 72 Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ogún ẹgbẹ̀rún dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún méjì mina fàdákà àti ẹẹ́tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà. 73 Àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Israẹli wà ní ìlú wọn. Nígbà tí ó di oṣù keje, tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú ìlú u wọn,

< Nehemiah 7 >