< Luke 7 >

1 Nígbà tí ó sì parí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ fun àwọn ènìyàn, ó wọ Kapernaumu lọ.
Cum autem implesset omnia verba sua in aures plebis, intravit Capharnaum.
2 Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ.
Centurionis autem cujusdam servus male habens, erat moriturus: qui illi erat pretiosus.
3 Nígbà tí ó sì gbúròó Jesu, ó rán àwọn àgbàgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá.
Et cum audisset de Jesu, misit ad eum seniores Judæorum, rogans eum ut veniret et salvaret servum ejus.
4 Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún.
At illi cum venissent ad Jesum, rogabant eum sollicite, dicentes ei: Quia dignus est ut hoc illi præstes:
5 Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, ó sì ti kọ́ Sinagọgu kan fún wa.”
diligit enim gentem nostram, et synagogam ipse ædificavit nobis.
6 Jesu sì ń bá wọn lọ. Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu, nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi.
Jesus autem ibat cum illis. Et cum jam non longe esset a domo, misit ad eum centurio amicos, dicens: Domine, noli vexari: non enim sum dignus ut sub tectum meum intres:
7 Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá, ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá.
propter quod et meipsum non sum dignum arbitratus ut venirem ad te: sed dic verbo, et sanabitur puer meus.
8 Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ; àti fún òmíràn pé, ‘Wá,’ a sì wá; àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”
Nam et ego homo sum sub potestate constitutus, habens sub me milites: et dico huic, Vade, et vadit: et alii, Veni, et venit: et servo meo, Fac hoc, et facit.
9 Nígbà tí Jesu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Israẹli.”
Quo audito Jesus miratus est: et conversus sequentibus se turbis, dixit: Amen dico vobis, nec in Israël tantam fidem inveni.
10 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ ọ̀dọ̀ náà tí ń ṣàìsàn, ara rẹ̀ ti dá.
Et reversi, qui missi fuerant, domum, invenerunt servum, qui languerat, sanum.
11 Ní ọjọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Naini, àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn.
Et factum est: deinceps ibat in civitatem quæ vocatur Naim: et ibant cum eo discipuli ejus et turba copiosa.
12 Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsi i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
Cum autem appropinquaret portæ civitatis, ecce defunctus efferebatur filius unicus matris suæ: et hæc vidua erat: et turba civitatis multa cum illa.
13 Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.”
Quam cum vidisset Dominus, misericordia motus super eam, dixit illi: Noli flere.
14 Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!”
Et accessit, et tetigit loculum. (Hi autem qui portabant, steterunt.) Et ait: Adolescens, tibi dico, surge.
15 Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
Et resedit qui erat mortuus, et cœpit loqui. Et dedit illum matri suæ.
16 Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn: wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé, “Wòlíì ńlá dìde nínú wa,” àti pé, “Ọlọ́run sì wá bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò!”
Accepit autem omnes timor: et magnificabant Deum, dicentes: Quia propheta magnus surrexit in nobis: et quia Deus visitavit plebem suam.
17 Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo Judea, àti gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.
Et exiit hic sermo in universam Judæam de eo, et in omnem circa regionem.
18 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu sì sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún un.
Et nuntiaverunt Joanni discipuli ejus de omnibus his.
19 Nígbà tí Johanu sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Olúwa, wí pé, “Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”
Et convocavit duos de discipulis suis Joannes, et misit ad Jesum, dicens: Tu es qui venturus es, an alium exspectamus?
20 Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Johanu onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, ‘Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’”
Cum autem venissent ad eum viri, dixerunt: Joannes Baptista misit nos ad te dicens: Tu es qui venturus es, an alium exspectamus?
21 Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti ààrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú.
(In ipsa autem hora multos curavit a languoribus, et plagis, et spiritibus malis, et cæcis multis donavit visum.)
22 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yin rí, tí ẹ̀yin sì gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòṣì ni à ń wàásù ìyìnrere.
Et respondens, dixit illis: Euntes renuntiate Joanni quæ audistis et vidistis: quia cæci vident, claudi ambulant, leprosi mundantur, surdi audiunt, mortui resurgunt, pauperes evangelizantur:
23 Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”
et beatus est quicumque non fuerit scandalizatus in me.
24 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Johanu pé, “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mì?
Et cum discessissent nuntii Joannis, cœpit de Joanne dicere ad turbas: Quid existis in desertum videre? arundinem vento agitatam?
25 Ṣùgbọ́n kín ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba!
Sed quid existis videre? hominem mollibus vestibus indutum? Ecce qui in veste pretiosa sunt et deliciis, in domibus regum sunt.
26 Ṣùgbọ́n kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Wòlíì? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ!
Sed quid existis videre? prophetam? Utique dico vobis, et plus quam prophetam:
27 Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé: “‘Wò ó, èmi yóò rán oníṣẹ́ mi síwájú rẹ; ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’
hic est, de quo scriptum est: Ecce mitto angelum meum ante faciem tuam, qui præparabit viam tuam ante te.
28 Mo wí fún yín nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí wòlíì tí ó pọ̀ ju Johanu Onítẹ̀bọmi lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kéré jùlọ ní ìjọba Ọlọ́run, ó pọ̀jù ú lọ.”
Dico enim vobis: major inter natos mulierum propheta Joanne Baptista nemo est: qui autem minor est in regno Dei, major est illo.
29 (Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Johanu tẹ̀ wọn bọ mi.
Et omnis populus audiens et publicani, justificaverunt Deum, baptizati baptismo Joannis.
30 Ṣùgbọ́n àwọn Farisi àti àwọn amòfin kọ ète Ọlọ́run fún ara wọn, a kò bamitiisi wọn lọ́dọ̀ rẹ̀.)
Pharisæi autem et legisperiti consilium Dei spreverunt in semetipsos, non baptizati ab eo.
31 Jesu sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ?
Ait autem Dominus: Cui ergo similes dicam homines generationis hujus? et cui similes sunt?
32 Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé, “‘Àwa fọn fèrè fún yín, ẹ̀yin kò jó, àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín, ẹ̀yin kò sọkún!’
Similes sunt pueris sedentibus in foro, et loquentibus ad invicem, et dicentibus: Cantavimus vobis tibiis, et non saltastis: lamentavimus, et non plorastis.
33 Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí wáìnì, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’
Venit enim Joannes Baptista, neque manducans panem, neque bibens vinum, et dicitis: Dæmonium habet.
34 Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Wò ó, ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀!’
Venit Filius hominis manducans, et bibens, et dicitis: Ecce homo devorator, et bibens vinum, amicus publicanorum et peccatorum.
35 Ṣùgbọ́n ọgbọ́n ni a dá láre nípasẹ̀ ọmọ rẹ.”
Et justificata est sapientia ab omnibus filiis suis.
36 Farisi kan sì rọ̀ ọ́ kí ó wá bá òun jẹun, ó sì wọ ilé Farisi náà lọ ó sì jókòó láti jẹun.
Rogabat autem illum quidam de pharisæis ut manducaret cum illo. Et ingressus domum pharisæi discubuit.
37 Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jesu jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ṣágo kékeré alabasita òróró ìkunra wá,
Et ecce mulier, quæ erat in civitate peccatrix, ut cognovit quod accubuisset in domo pharisæi, attulit alabastrum unguenti:
38 Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n.
et stans retro secus pedes ejus, lacrimis cœpit rigare pedes ejus, et capillis capitis sui tergebat, et osculabatur pedes ejus, et unguento ungebat.
39 Nígbà tí Farisi tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”
Videns autem pharisæus, qui vocaverat eum, ait intra se dicens: Hic si esset propheta, sciret utique quæ et qualis est mulier, quæ tangit eum: quia peccatrix est.
40 Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Simoni, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.” Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.”
Et respondens Jesus, dixit ad illum: Simon, habeo tibi aliquid dicere. At ille ait: Magister, dic.
41 “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbèsè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta.
Duo debitores erant cuidam fœneratori: unus debebat denarios quingentos, et alius quinquaginta.
42 Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríjì àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, ta ni yóò fẹ́ ẹ jù?”
Non habentibus illis unde redderent, donavit utrisque. Quis ergo eum plus diligit?
43 Simoni dáhùn wí pé, “Mo ṣe bí ẹni tí ó dáríjì jù ni.” Jesu wí fún un pé, “Ìwọ ti dájọ́ náà dáradára.”
Respondens Simon dixit: Æstimo quia is cui plus donavit. At ille dixit ei: Recte judicasti.
44 Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Simoni pé, “Wo obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹsẹ̀ fún mi: ṣùgbọ́n, omijé rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi ń nù wọ́n nù.
Et conversus ad mulierem, dixit Simoni: Vides hanc mulierem? Intravi in domum tuam, aquam pedibus meis non dedisti: hæc autem lacrimis rigavit pedes meos, et capillis suis tersit.
45 Ìwọ kò fi ìfẹnukonu fún mi: ṣùgbọ́n òun, nígbà tí mo ti wọ ilé, kò dẹ́kun ẹnu fífi kò mí lẹ́sẹ̀.
Osculum mihi non dedisti: hæc autem ex quo intravit, non cessavit osculari pedes meos.
46 Ìwọ kò fi òróró pa mí lórí, ṣùgbọ́n òun ti fi òróró pa mí lẹ́sẹ̀.
Oleo caput meum non unxisti: hæc autem unguento unxit pedes meos.
47 Ǹjẹ́ mo wí fún ọ, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í: nítorí tí ó ní ìfẹ́ púpọ̀: ẹni tí a sì dárí díẹ̀ jì, òun náà ni ó ní ìfẹ́ díẹ̀.”
Propter quod dico tibi: remittuntur ei peccata multa, quoniam dilexit multum. Cui autem minus dimittitur, minus diligit.
48 Ó sì wí fún un pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́!”
Dixit autem ad illam: Remittuntur tibi peccata.
49 Àwọn tí ó bá a jókòó jẹun sì bẹ̀rẹ̀ sí í rò nínú ara wọn pé, “Ta ni èyí tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni pẹ̀lú?”
Et cœperunt qui simul accumbebant, dicere intra se: Quis est hic qui etiam peccata dimittit?
50 Ó sì dáhùn wí fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ rẹ gbà ọ́ là, máa lọ ní àlàáfíà.”
Dixit autem ad mulierem: Fides tua te salvam fecit: vade in pace.

< Luke 7 >