< Job 39 >

1 “Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ? Ìwọ sì lè kíyèsi ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ? 2 Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pé, ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ. 3 Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bímọ, wọ́n sì mú ìkáàánú wọn jáde. 4 Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́n dàgbà nínú ọ̀dàn; wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn. 5 “Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́? Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó, 6 èyí tí mo fi aginjù ṣe ilé fún, àti ilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀. 7 Ó rẹ́rìn-ín sí ariwo ìlú, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbọ́ igbe darandaran. 8 Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjẹ oko rẹ̀, òun a sì máa wá ewé tútù gbogbo rí. 9 “Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí? Tàbí ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru? 10 Ìwọ le fi òkun tata de àgbáǹréré nínú aporo? Tàbí ó jẹ́ máa fa ìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn? 11 Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀lé e nítorí agbára rẹ̀ pọ̀? Ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́? 12 Ìwọ le gbẹ́kẹ̀lé pé, yóò mú èso oko rẹ̀ wá sílé, àti pé yóò sì kó ọ jọ sínú àká rẹ? 13 “Ìwọ ni yóò ha fi ìyẹ́ dáradára fún ọ̀kín bí, tàbí ìyẹ́ àti ìhùhù bo ògòǹgò? 14 Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀, a sì mú wọn gbóná nínú ekuru; 15 tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́, tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́. 16 Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀; asán ni iṣẹ́ rẹ̀ láìní ìbẹ̀rù; 17 nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un. 18 Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin. 19 “Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí, tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ? 20 Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà? Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá. 21 Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun. 22 Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà. 23 Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹkẹpẹkẹ, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta. 24 Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilé mi, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbà á gbọ́ pé, ìró ìpè ni. 25 Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà! Ó sì gbóhùn ogun lókèèrè réré, igbe àwọn balógun àti ìhó ayọ̀ ogun wọn. 26 “Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè, tí ó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsù? 27 Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè, kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga? 28 Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta, lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè. 29 Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ kiri, ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré. 30 Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀, níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”

< Job 39 >