< Ezra 2 >

1 Lákòókò náà, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Juda tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrín àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Babeli (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀. 2 Àwọn wọ̀nyí bá Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu àti Baanah wá). Iye àwọn ọkùnrin àwọn ènìyàn Israẹli. 3 Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án 4 Ṣefatia jẹ́ òjìdínnírinwó ó lé méjìlá 5 Arah jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n 6 Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ àwọn ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rin lé méjìlá 7 Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin 8 Sattu jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rún ó lé márùn-ún 9 Sakkai jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin 10 Bani jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì 11 Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlélógún 12 Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé méjìlélógún 13 Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà 14 Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta 15 Adini jẹ́ àádọ́ta lé ní irinwó ó lé mẹ́rin 16 Ateri (nípasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́run 17 Besai jẹ́ ọrùndínnírinwó ó lé mẹ́ta 18 Jora jẹ́ méjìléláàádọ́fà 19 Haṣumu jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún 20 Gibbari jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn. 21 Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà 22 Netofa jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta 23 Anatoti jẹ́ méjìdínláàádóje 24 Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì 25 Kiriati-Jearimu, Kefira àti Beeroti jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta 26 Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún 27 Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà 28 Beteli àti Ai jẹ́ igba ó lé mẹ́tàlélógún 29 Nebo jẹ́ méjìléláàádọ́ta 30 Magbiṣi jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ 31 Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta 32 Harimu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó. 33 Lodi, Hadidi àti Ono jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún 34 Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún 35 Senaa jẹ́ egbèji dín lógún ó lé ọgbọ̀n. 36 Àwọn àlùfáà. Àwọn ọmọ Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún dín lẹ́gbẹ̀rin ó dín méje 37 Immeri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì 38 Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta 39 Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún. 40 Àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ọmọ Jeṣua àti Kadmieli (ti ìdílé Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin. 41 Àwọn akọrin. Àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjìdínláàádóje. 42 Àwọn aṣọ́bodè. Àwọn ará Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita àti Ṣobai jẹ́ mọ́kàndínlógóje. 43 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. Àwọn ọmọ. Siha, Hasufa, Tabboati, 44 Kerosi, Siaha, Padoni, 45 Lebana, Hagaba, Akkubu, 46 Hagabu, Ṣalmai, Hanani, 47 Giddeli, Gahari, Reaiah, 48 Resini, Nekoda, Gassamu, 49 Ussa, Pasea, Besai, 50 Asna, Mehuni, Nefisimu, 51 Bakbu, Hakufa, Harhuri. 52 Basluti, Mehida, Harṣa, 53 Barkosi, Sisera, Tema, 54 Nesia àti Hatifa. 55 Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni. Àwọn ọmọ Sotai, Sofereti, Peruda, 56 Jaala, Darkoni, Giddeli, 57 Ṣefatia, àwọn ọmọ Hattili, Pokereti ti Haṣebaimu àti àwọn ọmọ Ami. 58 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ. 59 Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli. 60 Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì. 61 Àti nínú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà. Àwọn ọmọ: Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi a sì ń fi orúkọ náà pè é). 62 Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́. 63 Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu. 64 Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó. 65 Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀rin dín lẹ́gbàárin ó dín mẹ́tàlélọ́gọ́ta ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba akọrin ọkùnrin àti obìnrin. 66 Wọ́n ní ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin ẹṣin; ìbáaka òjìlélúgba ó lé márùn-ún, 67 ràkunmí jẹ́ irinwó ó lé márùndínlógójì àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rin lé lọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin. 68 Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀. 69 Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ́gbẹ̀rún ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún fàdákà àti ọgọ́rùn-ún ẹ̀wù àlùfáà. 70 Àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Israẹli ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.

< Ezra 2 >