< Exodus 32 >

1 Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mose pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Aaroni ká, wọ́n sì wí pé, “Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa. Bí ó ṣe ti Mose tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.”
וירא העם כי בשש משה לרדת מן ההר ויקהל העם על אהרן ויאמרו אליו קום עשה לנו אלהים אשר ילכו לפנינו כי זה משה האיש אשר העלנו מארץ מצרים לא ידענו מה היה לו׃
2 Aaroni dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bọ́ òrùka wúrà tí ó wà ní etí àwọn ìyàwó yín, tí àwọn ọmọkùnrin yín, àti tí àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi.”
ויאמר אלהם אהרן פרקו נזמי הזהב אשר באזני נשיכם בניכם ובנתיכם והביאו אלי׃
3 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ènìyàn bọ́ òrùka etí wọn, wọn sì kó wọn wá fún Aaroni.
ויתפרקו כל העם את נזמי הזהב אשר באזניהם ויביאו אל אהרן׃
4 Ó sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ó sì fi ṣe ohun ọnà fínfín, ó sì dà á ní àwòrán ẹgbọrọ màlúù. Nígbà náà ni wọn wí pé, “Israẹli, wọ̀nyí ni òrìṣà, ti ó mú un yín jáde wá láti Ejibiti.”
ויקח מידם ויצר אתו בחרט ויעשהו עגל מסכה ויאמרו אלה אלהיך ישראל אשר העלוך מארץ מצרים׃
5 Nígbà ti Aaroni rí èyí, ó kọ́ pẹpẹ kan níwájú ẹgbọrọ màlúù náà, ó sì kéde pé, “Lọ́la ni àjọyọ̀ sí Olúwa.”
וירא אהרן ויבן מזבח לפניו ויקרא אהרן ויאמר חג ליהוה מחר׃
6 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ àlàáfíà wá. Lẹ́yìn náà wọ́n jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣeré.
וישכימו ממחרת ויעלו עלת ויגשו שלמים וישב העם לאכל ושתו ויקמו לצחק׃
7 Olúwa sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú gòkè wá láti Ejibiti, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀.
וידבר יהוה אל משה לך רד כי שחת עמך אשר העלית מארץ מצרים׃
8 Wọ́n ti yí kánkán kúrò nípa ọ̀nà tí mo ti mo pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì ti dá ère ẹgbọrọ màlúù fún ara wọn. Wọ́n ti foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì ti rú ẹbọ sí i, wọ́n sì ti sọ pé, ‘Israẹli wọ̀nyí ní òrìṣà tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá.’”
סרו מהר מן הדרך אשר צויתם עשו להם עגל מסכה וישתחוו לו ויזבחו לו ויאמרו אלה אלהיך ישראל אשר העלוך מארץ מצרים׃
9 Olúwa wí fún Mose pé, “Èmi ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn.
ויאמר יהוה אל משה ראיתי את העם הזה והנה עם קשה ערף הוא׃
10 Ǹjẹ́ nísinsin yìí fi mí sílẹ̀, nítorí kí ìbínú mi lè gbóná sí wọn, kí Èmi sì lè pa wọ́n run. Nígbà náà ni Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.”
ועתה הניחה לי ויחר אפי בהם ואכלם ואעשה אותך לגוי גדול׃
11 Ṣùgbọ́n Mose kígbe fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Ejibiti wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára?
ויחל משה את פני יהוה אלהיו ויאמר למה יהוה יחרה אפך בעמך אשר הוצאת מארץ מצרים בכח גדול וביד חזקה׃
12 Èéṣe tí àwọn ará Ejibiti yóò ṣe wí pé, ‘Nítorí ibi ni ó ṣe mọ̀ ọ́n mọ̀ mú wọn jáde, láti pa wọ́n ní orí òkè àti láti gbá wọn kúrò lórí ayé’? Yípadà kúrò nínú ìbínú rẹ tí ó múná, yí ọkàn padà, kí o má sì ṣe mú ìparun wá sórí àwọn ènìyàn rẹ.
למה יאמרו מצרים לאמר ברעה הוציאם להרג אתם בהרים ולכלתם מעל פני האדמה שוב מחרון אפך והנחם על הרעה לעמך׃
13 Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, ẹni tí ìwọ búra fún fúnra rẹ̀, ‘Tí o wí fún wọn pé, Èmi yóò mú irú-ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Èmi yóò sì fún irú-ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’”
זכר לאברהם ליצחק ולישראל עבדיך אשר נשבעת להם בך ותדבר אלהם ארבה את זרעכם ככוכבי השמים וכל הארץ הזאת אשר אמרתי אתן לזרעכם ונחלו לעלם׃
14 Nígbà náà ni Olúwa dáwọ́ ìbínú rẹ̀ dúró, kò sì mú ìparun náà tí ó sọ wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́.
וינחם יהוה על הרעה אשר דבר לעשות לעמו׃
15 Mose sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú òkúta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin.
ויפן וירד משה מן ההר ושני לחת העדת בידו לחת כתבים משני עבריהם מזה ומזה הם כתבים׃
16 Iṣẹ́ Ọlọ́run sì ni wàláà náà; ìkọ̀wé náà jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run, a fín in sára àwọn òkúta wàláà náà.
והלחת מעשה אלהים המה והמכתב מכתב אלהים הוא חרות על הלחת׃
17 Nígbà tí Joṣua gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kígbe, ó sọ fún Mose pé, “Ariwo ogun wà nínú àgọ́.”
וישמע יהושע את קול העם ברעה ויאמר אל משה קול מלחמה במחנה׃
18 Mose dáhùn pé, “Kì í ṣe ariwo fún ìṣẹ́gun, kì í ṣe ariwo fún aṣẹ́gun; ohùn àwọn tí ń kọrin ni mo gbọ́.”
ויאמר אין קול ענות גבורה ואין קול ענות חלושה קול ענות אנכי שמע׃
19 Nígbà tí Mose dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì sọ wàláà ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ ní ìsàlẹ̀ òkè náà.
ויהי כאשר קרב אל המחנה וירא את העגל ומחלת ויחר אף משה וישלך מידו את הלחת וישבר אתם תחת ההר׃
20 Ó sì gbé ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó wọn; ó sì lọ̀ wọ́n kúnná, ó dà á sínú omi, ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli mu ún.
ויקח את העגל אשר עשו וישרף באש ויטחן עד אשר דק ויזר על פני המים וישק את בני ישראל׃
21 Mose sọ fún Aaroni pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?”
ויאמר משה אל אהרן מה עשה לך העם הזה כי הבאת עליו חטאה גדלה׃
22 Aaroni dáhùn wí pé, “Má ṣe bínú olúwa mi. Ìwọ mọ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe burú tó.
ויאמר אהרן אל יחר אף אדני אתה ידעת את העם כי ברע הוא׃
23 Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìṣà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mose ẹni tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá àwa kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.’
ויאמרו לי עשה לנו אלהים אשר ילכו לפנינו כי זה משה האיש אשר העלנו מארץ מצרים לא ידענו מה היה לו׃
24 Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí!”
ואמר להם למי זהב התפרקו ויתנו לי ואשלכהו באש ויצא העגל הזה׃
25 Mose rí pé àwọn ènìyàn náà kò ṣe ṣàkóso àti pé Aaroni ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrín àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.
וירא משה את העם כי פרע הוא כי פרעה אהרן לשמצה בקמיהם׃
26 Bẹ́ẹ̀ ni Mose dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún Olúwa, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Lefi sì péjọ yí i ká.
ויעמד משה בשער המחנה ויאמר מי ליהוה אלי ויאספו אליו כל בני לוי׃
27 Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, wí pé, ‘Kí olúkúlùkù ọkùnrin kí ó kọ idà rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ẹ lọ padà, kí ẹ jà láti àgọ́ kan dé òmíràn, olúkúlùkù kí ó pa arákùnrin rẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti aládùúgbò rẹ.’”
ויאמר להם כה אמר יהוה אלהי ישראל שימו איש חרבו על ירכו עברו ושובו משער לשער במחנה והרגו איש את אחיו ואיש את רעהו ואיש את קרבו׃
28 Àwọn ará Lefi ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kú tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ènìyàn.
ויעשו בני לוי כדבר משה ויפל מן העם ביום ההוא כשלשת אלפי איש׃
29 Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún Olúwa lónìí, nítorí ìwọ ti dìde sí àwọn ọmọ rẹ àti arákùnrin rẹ, ó sì ti bùkún fún ọ lónìí.”
ויאמר משה מלאו ידכם היום ליהוה כי איש בבנו ובאחיו ולתת עליכם היום ברכה׃
30 Ní ọjọ́ kejì Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi yóò gòkè lọ bá Olúwa; bóyá èmi lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”
ויהי ממחרת ויאמר משה אל העם אתם חטאתם חטאה גדלה ועתה אעלה אל יהוה אולי אכפרה בעד חטאתכם׃
31 Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn.
וישב משה אל יהוה ויאמר אנא חטא העם הזה חטאה גדלה ויעשו להם אלהי זהב׃
32 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.”
ועתה אם תשא חטאתם ואם אין מחני נא מספרך אשר כתבת׃
33 Olúwa dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, Èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.
ויאמר יהוה אל משה מי אשר חטא לי אמחנו מספרי׃
34 Ǹjẹ́ nísinsin yìí lọ, máa darí àwọn ènìyàn yìí lọ sí ibi ti mo sọ, angẹli mi yóò sì máa lọ ṣáájú yín. Ìgbà ń bọ̀ fún mi tì Èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò, Èmi yóò fi yà jẹ wọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
ועתה לך נחה את העם אל אשר דברתי לך הנה מלאכי ילך לפניך וביום פקדי ופקדתי עליהם חטאתם׃
35 Olúwa sì yọ àwọn ènìyàn náà lẹ́nu, pẹ̀lú ààrùn nítorí ohun tí wọ́n ṣe ní ti ẹgbọrọ màlúù tí Aaroni ṣe.
ויגף יהוה את העם על אשר עשו את העגל אשר עשה אהרן׃

< Exodus 32 >