< 1 Chronicles 14 >

1 Nísinsin yìí Hiramu àti ọba Tire rán oníṣẹ́ sí Dafidi, àti pẹ̀lú igi kedari pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un. 2 Dafidi sì mọ Israẹli àti pé Olúwa ti fi òun ṣe ọba lórí Israẹli àti pé ìjọba rẹ̀ ga jùlọ nítorí ti àwọn ènìyàn rẹ̀. 3 Ní Jerusalẹmu Dafidi mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di baba àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin. 4 Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣammua, Ṣobabu, Natani, Solomoni, 5 Ibhari, Eliṣua, Elifeleti, 6 Noga, Nefegi, Jafia, 7 Eliṣama, Beeliada, àti Elifeleti. 8 Nígbà tí àwọn ará Filistini gbọ́ pé a ti fi àmì òróró yàn Dafidi ní ọba lórí gbogbo Israẹli, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn. 9 Nísinsin yìí àwọn ará Filistini ti wá láti gbógun ti àfonífojì Refaimu; 10 Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé, “Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Filistini lọ bí? Ìwọ ó ha fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Olúwa sì wí fún un pé, “Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.” 11 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gòkè lọ sí Baali-Perasimu, níbẹ̀ ó sì kọlù wọ́n. Ó sí wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí omi tí ya jáde, Ọlọ́run ti ya Dafidi lórí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀lú ọwọ́ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń pè ibẹ̀ ní Baali-Perasimu. 12 Àwọn ará Filistini sì ti fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀. Dafidi sì pa á láṣẹ láti jó wọn nínú iná. 13 Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn ará Filistini gbógun wọ́n sì fọ́nká àfonífojì, 14 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì tún béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dalóhùn pé, “Má ṣe gòkè tààrà, ṣùgbọ́n ẹ yí wọn ká, kí ẹ sì mú wọn níwájú igi muliberi. 15 Tí ó bá sì ṣe, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ìró ẹsẹ̀ ní orí òkè igi muliberi, ẹ jáde fún ogun, nítorí èyí yóò fihàn pé Ọlọ́run ti jáde níwájú rẹ láti kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini.” 16 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini láti gbogbo ọ̀nà Gibeoni lọ sí Geseri. 17 Bẹ́ẹ̀ ni òkìkí Dafidi tàn ká gbogbo ilẹ̀ káàkiri, Olúwa sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè bẹ̀rù rẹ̀.

< 1 Chronicles 14 >