< کارهای رسولان 13 >

و در کلیسایی که در انطاکیه بود انبیا ومعلم چند بودند: برنابا و شمعون ملقب به نیجر و لوکیوس قیروانی و مناحم برادررضاعی هیرودیس تیترارخ و سولس. ۱ 1
Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Antioku; Barnaba àti Simeoni tí a ń pè ni Nigeri, àti Lukiu ará Kirene, àti Manaeni (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Herodu tetrarki) àti Saulu.
چون ایشان در عبادت خدا و روزه مشغول می‌بودند، روح‌القدس گفت: «برنابا و سولس را برای من جداسازید از بهر آن عمل که ایشان را برای آن خوانده‌ام.» ۲ 2
Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, “Ẹ ya Barnaba àti Saulu sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí!”
آنگاه روزه گرفته و دعا کرده ودستها بر ایشان گذارده، روانه نمودند. ۳ 3
Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.
پس ایشان از جانب روح‌القدس فرستاده شده، به سلوکیه رفتند و از آنجا از راه دریا به قپرس آمدند. ۴ 4
Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti rán àwọn méjèèjì lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Seleusia; láti ibẹ̀ wọ́n sì wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Saipurọsi.
و وارد سلامیس شده، در کنایس یهود به کلام خدا موعظه کردند و یوحنا ملازم ایشان بود. ۵ 5
Nígbà ti wọ́n sì wà ni Salami, wọ́n ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Sinagọgu àwọn Júù. Johanu náà sì wà pẹ̀lú wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ fún ìránṣẹ́ wọn.
و چون در تمامی جزیره تا به پافس گشتند، در آنجا شخص یهودی را که جادوگر ونبی کاذب بود یافتند که نام او باریشوع بود. ۶ 6
Nígbà tí wọ́n sì la gbogbo erékùṣù já dé Pafosi, wọ́n rí ọkùnrin oṣó àti wòlíì èké kan ti i ṣe Júù, orúkọ ẹni ti ó ń jẹ́ Bar-Jesu.
اورفیق سرجیوس پولس والی بود که مردی فهیم بود. همان برنابا و سولس را طلب نموده، خواست کلام خدا را بشنود. ۷ 7
Ó wà lọ́dọ̀ Segiu Paulusi baálẹ̀ ìlú náà tí í ṣe amòye ènìyàn. Òun náà ni ó ránṣẹ́ pe Barnaba àti Saulu, nítorí tí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
اما علیما یعنی آن جادوگر، زیرا ترجمه اسمش همچنین می‌باشد، ایشان رامخالفت نموده، خواست والی را از ایمان برگرداند. ۸ 8
Ṣùgbọ́n Elimu oṣó (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀) takò wọ́n, ó ń fẹ́ pa baálẹ̀ ni ọkàn dà kúrò ni ìgbàgbọ́.
ولی سولس که پولس باشد، پر ازروح‌القدس شده، بر او نیک نگریسته، ۹ 9
Ṣùgbọ́n Saulu ti a ń pè ni Paulu, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Elimu, ó sì wí pé,
گفت: «ای پر از هر نوع مکر و خباثت، ای فرزند ابلیس ودشمن هر راستی، باز نمی ایستی از منحرف ساختن طرق راست خداوند؟ ۱۰ 10
“Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ èṣù, ìwọ ọ̀tá ohun gbogbo, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po?
الحال دست خداوند بر توست و کور شده، آفتاب را تا مدتی نخواهی دید.» که در همان ساعت، غشاوه وتاریکی او را فرو گرفت و دور زده، راهنمایی طلب می‌کرد. ۱۱ 11
Ǹjẹ́ nísinsin yìí wò ó, ọwọ́ Olúwa ń bẹ lára rẹ̀, ìwọ ó sì fọjú ìwọ kì yóò rí oòrùn ní sá à kan!” Lójúkan náà, ìkùùkuu àti òkùnkùn sí bò ó; ó sì ń wá ènìyàn kiri láti fa òun lọ́wọ́ lọ.
پس والی چون آن ماجرا را دید، از تعلیم خداوند متحیر شده، ایمان آورد. ۱۲ 12
Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa.
آنگاه پولس و رفقایش از پافس به کشتی سوار شده، به پرجه پمفلیه آمدند. اما یوحنا ازایشان جدا شده، به اورشلیم برگشت. ۱۳ 13
Nígbà tí Paulu àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Pafosi wọ́n wá sí Perga ni Pamfilia: Johanu sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerusalẹmu.
و ایشان از پرجه عبور نموده، به انطاکیه پیسیدیه آمدند ودر روز سبت به کنیسه درآمده، بنشستند. ۱۴ 14
Nígbà ti wọ́n sì là Perga kọjá, wọ́n wá sí Pisidia ní Antioku. Wọ́n sì wọ inú Sinagọgu ní ọjọ́ ìsinmi, wọ́n sì jókòó.
وبعد از تلاوت تورات و صحف انبیا، روسای کنیسه نزد ایشان فرستاده، گفتند: «ای برادران عزیز، اگر کلامی نصیحت‌آمیز برای قوم دارید، بگویید.» ۱۵ 15
Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí Sinagọgu ránṣẹ́ sí wọn, pé, “Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́!”
پس پولس برپا ایستاده، به‌دست خوداشاره کرده، گفت: «ای مردان اسرائیلی وخداترسان، گوش دهید! ۱۶ 16
Paulu sì dìde dúró, ó sì juwọ́ sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin Israẹli, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fi etí sílẹ̀ sí mi!
خدای این قوم، اسرائیل، پدران ما را برگزیده، قوم را در غربت ایشان در زمین مصر سرافراز نمود و ایشان را به بازوی بلند از آنجا بیرون آورد؛ ۱۷ 17
Ọlọ́run àwọn ènìyàn Israẹli yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ejibiti, pẹ̀lú agbára ńlá ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀,
و قریب به چهل سال در بیابان متحمل حرکات ایشان می‌بود. ۱۸ 18
ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrù fún ìwà wọn ní ijù,
و هفت طایفه را در زمین کنعان هلاک کرده، زمین آنها را میراث ایشان ساخت تا قریب چهار صد و پنجاه سال. ۱۹ 19
nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kenaani, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní.
و بعد از آن بدیشان داوران داد تا زمان سموئیل نبی. ۲۰ 20
Gbogbo èyí sì ṣẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta lé ní irinwó ọdún. “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídàájọ́ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samuẹli wòlíì.
و از آن وقت پادشاهی خواستند و خدا شاول بن قیس را ازسبط بنیامین تا چهل سال به ایشان داد. ۲۱ 21
Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì béèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, ọkùnrin kan nínú ẹ̀yà Benjamini, fún ogójì ọdún.
پس اورا از میان برداشته، داود را برانگیخت تا پادشاه ایشان شود و در حق او شهادت داد که “داود بن یسی را مرغوب دل خود یافته‌ام که به تمامی اراده من عمل خواهد کرد.” ۲۲ 22
Nígbà ti ó sì mú Saulu kúrò, ó gbé Dafidi dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dafidi ọmọ Jese ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’
و از ذریت او خدابرحسب وعده، برای اسرائیل نجات‌دهنده‌ای یعنی عیسی را آورد، ۲۳ 23
“Láti inú irú-ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jesu Olùgbàlà dìde fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlérí.
چون یحیی پیش ازآمدن او تمام قوم اسرائیل را به تعمید توبه موعظه نموده بود. ۲۴ 24
Ṣáájú wíwá Jesu ni Johanu ti wàásù bamitiisi ìrònúpìwàdà fún gbogbo ènìyàn Israẹli.
پس چون یحیی دوره خودرا به پایان برد، گفت: “مرا که می‌پندارید؟ من اونیستم، لکن اینک بعد از من کسی می‌آید که لایق گشادن نعلین او نیم.” ۲۵ 25
Bí Johanu sì ti ńlá ipa tirẹ̀ já, ó ni, ‘Ta ni ẹ̀yin ṣe bí èmi jẹ́? Èmi kì í ṣe òun. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi í, ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú.’
«ای برادران عزیز و ابنای آل ابراهیم وهرکه از شما خداترس باشد، مر شما را کلام این نجات فرستاده شد. ۲۶ 26
“Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí.
زیرا سکنه اورشلیم وروسای ایشان، چونکه نه او را شناختند و نه آوازهای انبیا را که هر سبت خوانده می‌شود، بروی فتوی دادند و آنها را به اتمام رسانیدند. ۲۷ 27
Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi.
وهر‌چند هیچ علت قتل در وی نیافتند، از پیلاطس خواهش کردند که او کشته شود. ۲۸ 28
Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á.
پس چون آنچه درباره وی نوشته شده بود تمام کردند، او رااز صلیب پایین آورده، به قبر سپردند. ۲۹ 29
Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì.
لکن خدااو را از مردگان برخیزانید. ۳۰ 30
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú,
و او روزهای بسیار ظاهر شد بر آنانی که همراه او از جلیل به اورشلیم آمده بودند که الحال نزد قوم شهود او می‌باشند. ۳۱ 31
o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn.
پس ما به شما بشارت می‌دهیم، بدان وعده‌ای که به پدران ما داده شد، ۳۲ 32
“Àwa sì mú ìyìnrere wá fún yín pé, ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa,
که خدا آن را به ما که فرزندان ایشان می‌باشیم وفا کرد، وقتی که عیسی را برانگیخت، چنانکه در زبور دوم مکتوب است که “تو پسر من هستی، من امروز تو را تولیدنمودم.” ۳۳ 33
èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde, bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé, “‘Ìwọ ni Ọmọ mi; lónìí ni mo bí ọ.’
و در آنکه او را از مردگان برخیزانید تادیگر هرگز راجع به فساد نشود چنین گفت که “به برکات قدوس و امین داود برای شما وفا خواهم کرد.” ۳۴ 34
Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé: “‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’
بنابراین در جایی دیگر نیز می‌گوید: “توقدوس خود را نخواهی گذاشت که فساد را بیند.” ۳۵ 35
Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé, “‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’
زیرا که داود چونکه در زمان خود اراده خدا راخدمت کرده بود، به خفت و به پدران خود ملحق شده، فساد را دید. ۳۶ 36
“Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.
لیکن آن کس که خدا او رابرانگیخت، فساد را ندید. ۳۷ 37
Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́.
«پس‌ای برادران عزیز، شما را معلوم باد که به وساطت او به شما از آمرزش گناهان اعلام می‌شود. ۳۸ 38
“Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jesu yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín.
و به وسیله او هر‌که ایمان آورد، عادل شمرده می‌شود، از هر چیزی که به شریعت موسی نتوانستید عادل شمرده شوید. ۳۹ 39
Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose.
پس احتیاط کنید، مبادا آنچه در صحف انبیامکتوب است، بر شما واقع شود، ۴۰ 40
Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:
که “ای حقیرشمارندگان، ملاحظه کنید و تعجب نمایید و هلاک شوید زیرا که من عملی را درایام شما پدید آرم، عملی که هر‌چند کسی شما را از آن اعلام نماید، تصدیق نخواهیدکرد.» ۴۱ 41
“‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù; nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín, tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin.’”
پس چون از کنیسه بیرون می‌رفتند، خواهش نمودند که در سبت آینده هم این سخنان را بدیشان بازگویند. ۴۲ 42
Bí Paulu àti Barnaba sì ti ń jáde láti inú Sinagọgu, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀.
و چون اهل کنیسه متفرق شدند، بسیاری از یهودیان و جدیدان خداپرست از عقب پولس و برنابا افتادند؛ و آن دو نفر به ایشان سخن گفته، ترغیب می‌نمودند که به فیض خداثابت باشید. ۴۳ 43
Nígbà tí wọn sì jáde nínú Sinagọgu, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀lé Paulu àti Barnaba, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
اما در سبت دیگر قریب به تمامی شهر فراهم شدند تا کلام خدا را بشنوند. ۴۴ 44
Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ péjọ tan láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
ولی چون یهود ازدحام خلق را دیدند، از حسد پرگشتند و کفر گفته، با سخنان پولس مخالفت کردند. ۴۵ 45
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Paulu ń sọ.
آنگاه پولس و برنابا دلیر شده، گفتند: «واجب بود کلام خدا نخست به شما القا شود. لیکن چون آن را رد کردید و خود را ناشایسته حیات جاودانی شمردید، همانا به سوی امت هاتوجه نماییم. (aiōnios g166) ۴۶ 46
Paulu àti Barnaba sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà. (aiōnios g166)
زیرا خداوند به ما چنین امرفرمود که “تو را نور امت‌ها ساختم تا الی اقصای زمین منشا نجات باشی.”» ۴۷ 47
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé: “‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’”
چون امت‌ها این راشنیدند، شادخاطر شده، کلام خداوند را تمجیدنمودند و آنانی که برای حیات جاودانی مقرربودند، ایمان آوردند. (aiōnios g166) ۴۸ 48
Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́. (aiōnios g166)
و کلام خدا در تمام آن نواحی منتشرگشت. ۴۹ 49
A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbègbè náà.
اما یهودیان چند زن دیندار و متشخص و اکابر شهر را بشورانیدند و ایشان را به زحمت رسانیدن بر پولس و برنابا تحریض نموده، ایشان را از حدود خود بیرون کردند. ۵۰ 50
Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Paulu àti Barnaba, wọ́n sì le wọn kúrò ni agbègbè wọn.
و ایشان خاک پایهای خود را بر ایشان افشانده، به ایقونیه آمدند. ۵۱ 51
Ṣùgbọ́n wọ́n gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sí wọn, wọn sì wá sí Ikoniomu.
و شاگردان پر از خوشی و روح‌القدس گردیدند. ۵۲ 52
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.

< کارهای رسولان 13 >