< Corinthios I 7 >

1 De quibus autem scripsistis mihi: Bonum est homini mulierem non tangere:
Ní báyìí, nítorí àwọn ohun tí ẹ ṣe kọ̀wé: Ó dára fún ọkùnrin kí ó máa ṣe ni ìdàpọ̀ pẹ̀lú obìnrin.
2 propter fornicationem autem unusquisque suam uxorem habeat, et unaquaeque suum virum habeat.
Ṣùgbọ́n nítorí àgbèrè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan gbéyàwó tirẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní ọkọ tirẹ̀.
3 Uxori vir debitum reddat: similiter autem et uxor viro.
Kí ọkùnrin kí ó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ìyàwó rẹ̀ fún ún, kí ìyàwó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ọkọ fún ọkọ rẹ̀.
4 Mulier sui corporis potestatem non habet, sed vir. Similiter autem et vir sui corporis potestatem non habet, sed mulier.
Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ọkọ rẹ̀. Bákan náà ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ìyàwó rẹ̀.
5 Nolite fraudare invicem, nisi forte ex consensu ad tempus, ut vacetis orationi: et iterum revertimini in idipsum, ne tentet vos Satanas propter incontinentiam vestram.
Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ẹ̀tọ́ tọkọtaya wọ̀nyí dun ara yín, bí kò ṣe nípa ìfìmọ̀ṣọ̀kan, kí ẹ̀yin lè fi ara yín fún àwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ̀yin sì tún jùmọ̀ pàdé, lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ ara wọn kí Satani má ba à dán wọn wò nítorí àìlèmáradúró wọn.
6 Hoc autem dico secundum indulgentiam, non secundum imperium.
Mo sọ èyí fún un yín bí ìmọ̀ràn ní kì í ṣe bí àṣẹ.
7 Volo autem omnes vos esse sicut meipsum: sed unusquisque proprium donum habet ex Deo: alius quidem sic, alius vero sic.
Ó wù mí kí olúkúlùkù dàbí èmi, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn kò le jẹ́ bákan náà, Ọlọ́run fún olúkúlùkù ènìyàn ní ẹ̀bùn tirẹ̀, ọ̀kan bí irú èyí àti èkejì bí irú òmíràn.
8 Dico autem non nuptis, et viduis: bonum est illis si sic permaneant, sicut et ego.
Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọ́n kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà.
9 Quod si non se continent, nubant. Melius est enim nubere, quam uri.
Ṣùgbọ́n bí wọ́n kò bá lè mú ara dúró, kí wọ́n gbéyàwó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyàwó jù láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ.
10 Iis autem, qui matrimonio iuncti sunt, praecipio non ego, sed Dominus, uxorem a viro non discedere:
Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ kọ́ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.”
11 quod si discesserit, manere innuptam, aut viro suo reconciliari. Et vir uxorem non dimittat.
Ṣùgbọ́n tí ó bá fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ làjà, kí ọkọ kí ó má ṣe aya rẹ̀ sílẹ̀.
12 Nam ceteris ego dico, non Dominus. Si quis frater uxorem habet infidelem, et haec consentit habitare cum illo, non dimittat illam.
Mo fẹ́ fi àwọn ìmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ́ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
13 Et si qua mulier fidelis habet virum infidelem, et hic consentit habitare cum illa, non dimittat virum:
Tí ó bá sì jẹ́ obìnrin ló fẹ́ ọkọ tí kò gbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà ń fẹ́ kí obìnrin yìí dúró tí òun, aya náà kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
14 sanctificatus est enim vir infidelis per mulierem fidelem, et sanctificata est mulier infidelis per virum fidelem: alioquin filii vestri immundi essent, nunc autem sancti sunt.
Nítorí pé ó ṣe é ṣe kí a lè mú ọkọ tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa aya tí í ṣe onígbàgbọ́, a sì le mú ìyàwó tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ aláìmọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí àwọn ọmọ wọn di mímọ́.
15 Quod si infidelis discedit, discedat: non enim servituti subiectus est frater, aut soror in huiusmodi: in pace autem vocavit nos Deus.
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin tí i ṣe aláìgbàgbọ́ náà bá fẹ́ láti lọ, jẹ́ kí ó máa lọ. Arákùnrin tàbí arábìnrin náà kò sí lábẹ́ ìdè mọ́; Ọlọ́run ti pè wá láti gbé ní àlàáfíà.
16 Unde enim scis mulier, si virum salvum facies? aut unde scis vir, si mulierem salvam facies?
Báwo ni ẹ̀yin aya ṣe le mọ̀ pé bóyá ẹ̀yin ni yóò gba ọkọ yín là? Bákan náà ni a lè wí nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́ pé, kò sí ìdánilójú pé aya aláìgbàgbọ́ le yípadà láti di onígbàgbọ́ nípa dídúró ti ọkọ.
17 nisi unicuique sicut divisit Dominus, unumquemque sicut vocavit Deus, ita ambulet, et sicut in omnibus Ecclesiis doceo.
Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù máa gbé ìgbé ayé tí Ọlọ́run ń fẹ́ yín fún, àti nínú èyí tí Olúwa pè é sí. Ìlànà àti òfin mi fún gbogbo ìjọ ni èyí.
18 Circumcisus aliquis vocatus est? non adducat praeputium. In praeputio aliquis vocatus est? non circumcidatur.
Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó má sì ṣe di aláìkọlà. Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó ma ṣe kọlà.
19 Circumcisio nihil est, et praeputium nihil est: sed observatio mandatorum Dei.
Ìkọlà kò jẹ́ nǹkan àti àìkọlà kò jẹ́ nǹkan, bí kò ṣe pípa òfin Ọlọ́run mọ́.
20 Unusquisque in qua vocatione vocatus est, in ea permaneat.
Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa ṣe iṣẹ́ tí ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí Ọlọ́run tó pé é sínú ìgbàgbọ́ nínú Kristi.
21 Servus vocatus es? non sit tibi curae: sed et si potes fieri liber, magis utere.
Ǹjẹ́ ẹrú ni ọ́ bí nígbà ti a pè ọ́? Má ṣe kà á sí. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá le di òmìnira, kúkú ṣe èyí nì.
22 Qui enim in Domino vocatus est servus, libertus est Domini: similiter qui liber vocatus est, servus est Christi.
Tí ó bá jẹ́ ẹrú, ti Olúwa sì pé ọ, rántí pé Kristi ti sọ ọ́ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára búburú ti ẹ̀ṣẹ̀. Tí ó bá sì ti pé ọ̀ nítòótọ́ tí ó sì ti di òmìnira, ó ti di ẹrú Kristi.
23 Pretio empti estis, nolite fieri servi hominum.
A sì ti rà yín ní iye kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn.
24 Unusquisque ergo in quo vocatus est frater, in hoc permaneat apud Deum.
Ará, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn, nínú èyí tí a pè é, kí ó dúró nínú ọ̀kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run.
25 De virginibus autem praeceptum Domini non habeo: consilium autem do, tamquam misericordiam consecutus a Domino, ut sim fidelis.
Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn wúńdíá, èmi kò ní àṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo wí fún yín ní ìdájọ́ bí ẹni tí ó rí àánú Olúwa gbà láti jẹ́ olódodo.
26 Existimo enim hoc bonum esse propter instantem necessitatem, quoniam bonum est homini sic esse.
Nítorí náà mo rò pé èyí dára nítorí wàhálà ìsinsin yìí, èyí nì ni pé o dára fún ènìyàn kí ó wà bí o ṣe wà.
27 Alligatus es uxori? noli quaerere solutionem. Solutus es ab uxore? noli quaerere uxorem.
Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹlẹ́rìí láti fẹ́ ìyàwó. Ẹ má ṣe kọ ara yín sílẹ̀, nítorí èyí tí mo wí yìí. Ṣùgbọ́n tí o kò bá sì tí ìgbéyàwó, tàbí fẹ́ ọkọ, má ṣe sáré láti ṣe bẹ́ẹ̀ lákokò yìí.
28 Si autem acceperis uxorem: non peccasti. Et si nupserit virgo, non peccavit. tribulationem tamen carnis habebunt huiusmodi. Ego autem vobis parco.
Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá gbé ìyàwó ìwọ kò dẹ́ṣẹ̀, bí a bá gbé wúńdíá ní ìyàwó òun kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó bá gbé ìyàwó yóò dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nípa ti ara, ṣùgbọ́n èmi fẹ́ dá a yín sí.
29 Hoc itaque dico, fratres: Tempus breve est: reliquum est, ut et qui habent uxores, tamquam non habentes sint:
Òun ti mo ń wí ará, ni pé kúkúrú ni àkókò, láti ìsinsin yìí lọ, ẹni tí ó ni aya kí ó dàbí ẹni tí kò ní rí;
30 et qui flent, tamquam non flentes: et qui gaudent, tamquam non gaudentes: et qui emunt, tamquam non possidentes:
àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí,
31 et qui utuntur hoc mundo, tamquam non utantur: praeterit enim figura huius mundi.
àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn: nítorí ìgbà ayé yìí ń kọjá lọ.
32 Volo autem vos sine solicitudine esse. Qui sine uxore est, solicitus est quae Domini sunt, quomodo placeat Deo.
Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn.
33 Qui autem cum uxore est, solicitus est quae sunt mundi, quomodo placeat uxori, et divisus est.
Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn,
34 Et mulier innupta, et virgo cogitat quae Domini sunt, ut sit sancta corpore, et spiritu. Quae autem nupta est, cogitat quae sunt mundi, quomodo placeat viro.
dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí a gbé ní ìyàwó àti wúńdíá. Obìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa tọ́jú ohun tí ṣe ti Olúwa, kí òun lè jẹ́ mímọ́ ní ara àti ní ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe ìtọ́jú ohun tí ṣe ti ayé, bí yóò ti ṣe le tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn.
35 Porro hoc ad utilitatem vestram dico: non ut laqueum vobis iniiciam, sed ad id, quod honestum est, et quod facultatem praebeat sine impedimento Dominum obsecrandi.
Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn.
36 Si quis autem turpem se videri existimat super virgine sua, quod sit superadulta, et ita oportet fieri: quod vult faciat: non peccat, si nubat.
Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun kò ṣe ohun tí ó yẹ sí wúńdíá rẹ̀ ti ìpòùngbẹ rẹ si pọ si, bí ó bá sí tọ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ó ṣe bí ó tí fẹ́, òun kò dẹ́ṣẹ̀, jẹ́ kí wọn gbé ìyàwó.
37 Nam qui statuit in corde suo firmus, non habens necessitatem, potestatem autem habens suae voluntatis, et hoc iudicavit in corde suo, servare virginem suam, bene facit.
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, tí kò ní àìgbọdọ̀ má ṣe, ṣùgbọ́n tí ó ní agbára lórí ìfẹ́ ara rẹ̀, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn rẹ̀ pé, òun ó pa wúńdíá ọmọbìnrin òun mọ́, yóò ṣe rere.
38 Igitur et qui matrimonio iungit virginem suam, bene facit: et qui non iungit, melius facit.
Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹni tí ó fi wúńdíá ọmọbìnrin fún ni ní ìgbéyàwó, ó ṣe rere; ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi fún ni ní ìgbéyàwó ṣe rere jùlọ.
39 Mulier alligata est legi quanto tempore vir eius vivit. quod si dormierit vir eius, liberata est: cui vult nubat: tantum in Domino.
A fi òfin dé obìnrin níwọ̀n ìgbà tí òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ wà láààyè, bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn, tí ó bá wù ú ó sì gbọdọ̀ jẹ́ ti Olúwa.
40 Beatior autem erit si sic permanserit secundum meum consilium: puto autem quod et ego Spiritum Dei habeam.
Ṣùgbọ́n nínú èrò tèmi obìnrin náà yóò ní ayọ̀ púpọ̀, tí kò bá ṣe ìgbéyàwó mìíràn mọ́. Mo sì rò pé mo ń fún un yín ní ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run nígbà tí mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.

< Corinthios I 7 >