< Corinthios I 5 >

1 Omnino auditur inter vos fornicatio, et talis fornicatio, qualis nec inter Gentes, ita ut uxorem patris sui aliquis habeat.
Ìròyìn rẹ ń tàn kalẹ̀ pé ìwà àgbèrè wa láàrín yín, irú àgbèrè tí a kò tilẹ̀ gbúròó rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà pé, ẹnìkan nínú yín ń fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀.
2 Et vos inflati estis: et non magis luctum habuistis ut tollatur de medio vestrum qui hoc opus fecit.
Ẹ̀yin ń ṣe ìgbéraga! Ẹ̀yin kò kúkú káàánú kí a lè mú ẹni tí ó hu ìwà yìí kúrò láàrín yín?
3 Ego quidem absens corpore, praesens autem spiritu, iam iudicavi ut praesens, eum, qui sic operatus est,
Lóòtítọ́ èmi kò sí láàrín yín nípa ti ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí àti pé, ní orúkọ Olúwa Jesu Kristi, mo tí ṣe ìdájọ́ lórí irú ẹni bẹ́ẹ̀, bí ẹni pé mo wá láàrín yín.
4 in nomine Domini nostri Iesu Christi, congregatis vobis et meo spiritu, cum virtute Domini nostri Iesu,
Ní orúkọ Jesu Kristi. Nígbà tí ẹ̀yin bá péjọ, àti ẹ̀mí mi si wa pẹ̀lú yin nínú ẹ̀mí mi àti pẹ̀lú agbára Jesu Kristi Olúwa wa.
5 tradere huiusmodi hominem satanae in interitum carnis, ut spiritus salvus sit in die Domini nostri Iesu Christi.
Kí ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ lé Satani lọ́wọ́ fún ìparun ara, kí ó ba à le gba ẹ̀mí rẹ là ní ọjọ́ Olúwa wa Jesu Kristi.
6 Non est bona gloriatio vestra. Nescitis quia modicum fermentum totam massam corrumpit?
Ìṣeféfé yín kò dára. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní mú gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú?
7 Expurgate vetus fermentum, ut sitis nova conspersio, sicut estis azymi. Etenim Pascha nostrum immolatus est Christus.
Nítorí náà ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò nínú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ìyẹ̀fun tuntun, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà. Nítorí à ti fi ìrékọjá wa, àní Kristi ni a ti pa láti fi ṣe ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.
8 Itaque epulemur: non in fermento veteri, neque in fermento malitiae, et nequitiae: sed in azymis sinceritatis, et veritatis.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankàn àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo.
9 Scripsi in epistola: Ne commisceamini fornicariis.
Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ènìyàn.
10 non utique fornicariis huius mundi, aut avaris, aut rapacibus, aut idolis servientibus: alioquin debueratis de hoc mundo exiisse.
Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà. Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn.
11 Nunc autem scripsi vobis non commisceri: si is, qui frater nominatur inter vos, est fornicator, aut avarus, aut idolis serviens, aut maledicus, aut ebriosus, aut rapax: cum eiusmodi nec cibum sumere.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí mo kọ̀wé sí i yín pé, bí ẹnikẹ́ni tí a pe rẹ̀ ni arákùnrin bá jẹ́ àgbèrè, tàbí wọ̀bìà, tàbí abọ̀rìṣà, àti ẹlẹ́gàn, tàbí ọ̀mùtípara, tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà. Kí ẹ tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.
12 Quid enim mihi de iis, qui foris sunt, iudicare? Nonne de iis, qui intus sunt, vos iudicatis?
Nítorí èwo ni tèmi láti máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń bẹ lóde? Kì í ha ṣe àwọn tí ó wà nínú ni ẹ̀yin ṣe ìdájọ́ wọn?
13 nam eos, qui foris sunt, Deus iudicabit. Auferte malum ex vobisipsis.
Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ àwọn tí ó ń bẹ lóde. “Ẹ lé àwọn ènìyàn búburú náà kúrò láàrín yín.”

< Corinthios I 5 >