< 民数記 28 >

1 主はモーセに言われた、
Olúwa sọ fún Mose pé,
2 「イスラエルの人々に命じて言いなさい、『あなたがたは香ばしいかおりとしてわたしにささげる火祭、すなわち、わたしの供え物、わたしの食物を定めの時にわたしにささげることを怠ってはならない』。
“Fún àwọn ọmọ Israẹli ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi.’
3 また彼らに言いなさい、『あなたがたが主にささぐべき火祭はこれである。すなわち一歳の雄の全き小羊二頭を毎日ささげて常燔祭としなければならない。
Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa: akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun ní ojoojúmọ́.
4 すなわち一頭の小羊を朝にささげ、一頭の小羊を夕にささげなければならない。
Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.
5 また麦粉一エパの十分の一に、砕いて取った油一ヒンの四分の一を混ぜて素祭としなければならない。
Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ tí ó jẹ́ ìdámẹ́wàá efa ìyẹ̀fun dáradára tí a pò mọ́ ìdámẹ́rin hínì òróró tí a yọ lára Olifi.
6 これはシナイ山で定められた常燔祭であって、主に香ばしいかおりとしてささげる火祭である。
Èyí ni ẹbọ sísun gbogbo ìgbà tí a fi lélẹ̀ ní òkè Sinai gẹ́gẹ́ bí olóòórùn dídùn ẹbọ tí a fi iná sun fún Olúwa pẹ̀lú iná.
7 またその灌祭は小羊一頭について一ヒンの四分の一をささげなければならない。すなわち聖所において主のために濃い酒をそそいで灌祭としなければならない。
Àfikún ọrẹ ohun mímu rẹ gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́rin ti hínì dídé omi mímu tí ó kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn. Da ẹbọ mímu náà síta sí Olúwa ní ibi mímọ́.
8 夕には他の一頭の小羊をささげなければならない。その素祭と灌祭とは朝のものと同じようにし、その小羊を火祭としてささげ、主に香ばしいかおりとしなければならない。
Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ní àfẹ̀mọ́júmọ́, pẹ̀lú oríṣìí ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu èyí tí ó pèsè ní òwúrọ̀, èyí ni ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòórùn dídùn sí Olúwa.
9 また安息日には一歳の雄の全き小羊二頭と、麦粉一エパの十分の二に油を混ぜた素祭と、その灌祭とをささげなければならない。
“‘Ní ọjọ́ ìsinmi, pèsè akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ohun jíjẹ tí i ṣe ìdá méjì nínú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò.
10 これは安息日ごとの燔祭であって、常燔祭とその灌祭とに加えらるべきものである。
Èyí ni ẹbọ sísun fún gbogbo ọjọ́ ìsinmi kọ̀ọ̀kan, ní àfikún pẹ̀lú ẹbọ sísun àti ẹbọ ohun mímu.
11 またあなたがたは月々の第一日に燔祭を主にささげなければならない。すなわち若い雄牛二頭、雄羊一頭、一歳の雄の全き小羊七頭をささげ、
“‘Àti ní ọjọ́ tí o bẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan, kí ẹ̀yin kí ó gbé ẹbọ sísun fún Olúwa pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù.
12 雄牛一頭には麦粉一エパの十分の三に油を混ぜたものを素祭とし、雄羊一頭には麦粉一エパの十分の二に油を混ぜたものを素祭とし、
Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ ẹbọ ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ pẹ̀lú òróró; pẹ̀lú àgbò, ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ tí í ṣe ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ mọ́ òróró;
13 小羊一頭には麦粉十分の一に油を混ぜたものを素祭とし、これを香ばしいかおりの燔祭として主のために火祭としなければならない。
pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn, ni kí ẹ rú ẹbọ ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò mọ́ òróró. Èyí ni ẹbọ sísun, òórùn dídùn, àti ẹbọ tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú iná.
14 またその灌祭は雄牛一頭についてぶどう酒一ヒンの二分の一、雄羊一頭について一ヒンの三分の一、小羊一頭について一ヒンの四分の一をささげなければならない。これは年の月々を通じて、新月ごとにささぐべき燔祭である。
Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òsùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún.
15 また常燔祭とその灌祭とのほかに、雄やぎ一頭を罪祭として主にささげなければならない。
Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
16 正月の十四日は主の過越の祭である。
“‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ni ìrékọjá Olúwa gbọdọ̀ wáyé.
17 またその月の十五日は祭日としなければならない。七日のあいだ種入れぬパンを食べなければならない。
Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.
18 その初めの日には聖会を開かなければならない。なんの労役をもしてはならない。
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan.
19 あなたがたは火祭として主に燔祭をささげなければならない。すなわち若い雄牛二頭、雄羊一頭、一歳の雄の小羊七頭をささげなければならない。これらはみな全きものでなければならない。
Ẹ rú ẹbọ sísun sí Olúwa, ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù.
20 その素祭には油を混ぜた麦粉をささげなければならない。すなわち雄牛一頭につき麦粉一エパの十分の三、雄羊一頭につき十分の二をささげ、
Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá;
21 また七頭の小羊にはその一頭ごとに十分の一をささげなければならない。
pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan ìdákan nínú mẹ́wàá.
22 また雄やぎ一頭を罪祭としてささげ、あなたがたのために罪のあがないをしなければならない。
Pẹ̀lú òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún un yín.
23 あなたがたは朝にささげる常燔祭の燔祭のほかに、これらをささげなければならない。
Ṣe eléyìí ní àfikún sí ẹbọ sísun àràárọ̀.
24 このようにあなたがたは七日のあいだ毎日、火祭の食物をささげて、主に香ばしいかおりとしなければならない。これは常燔祭とその灌祭とのほかにささぐべきものである。
Báyìí ní kí ẹ̀yin rúbọ ní ọjọọjọ́, jálẹ̀ ní ọjọ́ méjèèje, oúnjẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí olóòórùn dídùn sí Olúwa; ó rú u pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu.
25 そして第七日に、あなたがたは聖会を開かなければならない。なんの労役をもしてはならない。
Ní ọjọ́ keje kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.
26 あなたがたは七週の祭、すなわち新しい素祭を主にささげる初穂の日にも聖会を開かなければならない。なんの労役をもしてはならない。
“‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.
27 あなたがたは燔祭をささげて、主に香ばしいかおりとしなければならない。すなわち若い雄牛二頭、雄羊一頭、一歳の雄の小羊七頭をささげなければならない。
Kí ẹ mú ẹbọ sísun ẹgbọrọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn fún Olúwa.
28 その素祭には油を混ぜた麦粉をささげなければならない。すなわち雄牛一頭につき一エパの十分の三、雄羊一頭につき十分の二をささげ、
Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù ní kí ẹ rú ẹbọ ohun mímu ìdámẹ́ta pẹ̀lú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò pẹ̀lú àgbò kan.
29 また七頭の小羊には一頭ごとに十分の一をささげなければならない。
Àti pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn méje, kí ó jẹ́ ìdákan nínú mẹ́wàá.
30 また雄やぎ一頭をささげてあなたがたのために罪のあがないをしなければならない。
Ẹ fi òbúkọ kan ṣe ètùtù fún ara yín.
31 あなたがたは常燔祭とその素祭とその灌祭とのほかに、これらをささげなければならない。これらはみな、全きものでなければならない。
Kí ẹ̀yin kí ó rú wọn pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu yín àti ẹbọ ohun jíjẹ yín. Kí ẹ sì ri dájú pé àwọn ẹranko náà jẹ́ aláìlábùkù.

< 民数記 28 >