< תהילים 71 >

בך-יהוה חסיתי אל-אבושה לעולם 1
Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò; má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
בצדקתך תצילני ותפלטני הטה-אלי אזנך והושיעני 2
Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ; dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
היה לי לצור מעון לבוא-- תמיד צוית להושיעני כי-סלעי ומצודתי אתה 3
Jẹ́ àpáta ààbò mi, níbi tí èmi lè máa lọ, pa àṣẹ láti gbà mí, nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
אלהי--פלטני מיד רשע מכף מעול וחומץ 4
Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú, ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.
כי-אתה תקותי אדני יהוה מבטחי מנעורי 5
Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè, ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
עליך נסמכתי מבטן--ממעי אמי אתה גוזי בך תהלתי תמיד 6
Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi; Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
כמופת הייתי לרבים ואתה מחסי-עז 7
Mo di àmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
ימלא פי תהלתך כל-היום תפארתך 8
Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi, ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.
אל-תשליכני לעת זקנה ככלות כחי אל-תעזבני 9
Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́.
כי-אמרו אויבי לי ושמרי נפשי נועצו יחדו 10
Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi, àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.
לאמר אלהים עזבו רדפו ותפשוהו כי-אין מציל 11
Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu, nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
אלהים אל-תרחק ממני אלהי לעזרתי חישה (חושה) 12
Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run; wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.
יבשו יכלו שטני נפשי יעטו חרפה וכלמה--מבקשי רעתי 13
Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú, kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.
ואני תמיד איחל והוספתי על-כל-תהלתך 14
Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi; èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.
פי יספר צדקתך--כל-היום תשועתך כי לא ידעתי ספרות 15
Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ, ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́, lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.
אבוא--בגברות אדני יהוה אזכיר צדקתך לבדך 16
Èmi ó wá láti wá kéde agbára, Olúwa Olódùmarè; èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.
אלהים למדתני מנעורי ועד-הנה אגיד נפלאותיך 17
Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.
וגם עד-זקנה ושיבה-- אלהים אל-תעזבני עד-אגיד זרועך לדור לכל-יבוא גבורתך 18
Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi, títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.
וצדקתך אלהים עד-מרום אשר-עשית גדלות אלהים מי כמוך 19
Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run, ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá. Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?
אשר הראיתנו (הראיתני) צרות רבות-- ורעות תשוב תחינו (תחיני) ומתהמות הארץ תשוב תעלני 20
Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀.
תרב גדלתי ותסב תנחמני 21
Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.
גם-אני אודך בכלי-נבל-- אמתך אלהי אזמרה לך בכנור-- קדוש ישראל 22
Èmi yóò fi dùùrù mi yìn fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi; èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
תרננה שפתי כי אזמרה-לך ונפשי אשר פדית 23
Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ: èmi, ẹni tí o rà padà.
גם-לשוני-- כל-היום תהגה צדקתך כי-בשו כי-חפרו מבקשי רעתי 24
Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́, fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára, a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

< תהילים 71 >