< 1 Samuel 31 >

1 Now the Philistines fought against Israel: and the men of Israel fled from before the Philistines, and fell down slain on Mount Gilboa.
Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa.
2 The Philistines followed hard on Saul and on his sons; and the Philistines killed Jonathan, and Abinadab, and Malkishua, the sons of Saul.
Àwọn Filistini sì ń lépa Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ kíkan; àwọn Filistini sì pa Jonatani àti Abinadabu, àti Malikiṣua, àwọn ọmọ Saulu.
3 The battle was fierce against Saul, and the archers found him, and he was wounded by the archers.
Ìjà náà sì burú fún Saulu gidigidi, àwọn tafàtafà si ta á ní ọfà, o sì fi ara pa púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn tafàtafà.
4 Then Saul said to his armor bearer, "Draw your sword, and thrust me through with it, lest these uncircumcised come and thrust me through, and torture me." But his armor bearer would not; for he was terrified. Therefore Saul took his sword, and fell on it.
Saulu sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí ìwọ sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má ba à wá gún mi, àti kí wọn kí ó má bá à fi mí ṣe ẹlẹ́yà.” Ṣùgbọ́n ẹni tí ó rú ẹ̀rù ìhámọ́ra rẹ̀ kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹ̀rù bà á gidigidi. Nígbà náà ni Saulu mú idà, ó sì ṣubú lù ú.
5 When his armor bearer saw that Saul was dead, he likewise fell on his sword, and died with him.
Nígbà tí ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ si rí i pé Saulu kú, òun náà sì fi idà rẹ̀ pa ara rẹ̀, ó sì kú pẹ̀lú rẹ̀.
6 So Saul died, and his three sons, and his armor bearer, and all his men, that same day together.
Saulu sì kú, àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta, àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.
7 When the men of Israel who were on the other side of the valley, and those who were beyond the Jordan, saw that the men of Israel fled, and that Saul and his sons were dead, they abandoned their cities, and fled; and the Philistines came and lived in them.
Nígbà ti àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó wà lápá kejì àfonífojì náà, àti àwọn ẹni tí ó wà lápá kejì Jordani, rí pé àwọn ọkùnrin Israẹli sá, àti pé Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ ti kú, wọ́n sì fi ìlú sílẹ̀, wọ́n sì sá, àwọn Filistini sì wá, wọ́n sì jókòó si ìlú wọn.
8 It happened on the next day, when the Philistines came to strip the slain, that they found Saul and his three sons fallen on Mount Gilboa.
Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn Filistini dé láti bọ́ nǹkan tí ń bẹ lára àwọn tí ó kù, wọ́n sì rí pé, Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta ṣubú ni òkè Gilboa.
9 They cut off his head, and stripped off his armor, and sent into the land of the Philistines all around, to carry the news to their idols, and to the people.
Wọ́n sì gé orí rẹ̀, wọ́n sì bọ ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ lọ ilẹ̀ Filistini káàkiri, láti máa sọ ọ́ ní gbangba ni ilé òrìṣà wọn, àti láàrín àwọn ènìyàn.
10 They put his armor in the house of the Ashtaroth; and they fastened his body to the wall of Beth Shan.
Wọ́n sì fi ìhámọ́ra rẹ̀ sí ilé Aṣtoreti: wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ odi Beti-Ṣani.
11 But when the inhabitants of Jabesh Gilead heard what the Philistines had done to Saul,
Nígbà tí àwọn ará Jabesi Gileadi sì gbọ́ èyí tí àwọn Filistini ṣe sí Saulu.
12 all the valiant men arose and traveled all night, and took the body of Saul and the bodies of his sons from the wall of Beth Shan, and brought them to Jabesh and burnt them there.
Gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára sì dìde, wọ́n sì fi gbogbo òru náà rìn, wọ́n sì gbé òkú Saulu, àti òkú àwọn ọmọ bíbí rẹ̀ kúrò lára odi Beti-Ṣani, wọ́n sì wá sí Jabesi, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀.
13 They took their bones, and buried them under the tamarisk tree in Jabesh, and fasted seven days.
Wọ́n sì kó egungun wọn, wọ́n sì sin wọ́n lábẹ́ igi tamariski ní Jabesi, wọ́n sì gbààwẹ̀ ní ọjọ́ méje.

< 1 Samuel 31 >