< 1 Samuel 11 >

1 Then Nahash the Ammonite came vp, and besieged Iabesh Gilead: and all the men of Iabesh saide vnto Nahash, Make a couenant with vs, and we will be thy seruants.
Nahaṣi ará Ammoni gòkè lọ, ó sì dó ti Jabesi Gileadi, gbogbo ọkùnrin Jabesi sì wí fún Nahaṣi pé, “Bá wa dá májẹ̀mú, àwa yóò sì máa sìn ọ́.”
2 And Nahash ye Ammonite answered them, On this condition will I make a couenant with you, that I may thrust out all your right eies, and bring that shame vpon all Israel.
Ṣùgbọ́n Nahaṣi ará Ammoni sì wí fún un pé, “Nípa èyí ni èmi yóò fi bá a yín ṣe ìpinnu, nípa yíyọ gbogbo ojú ọ̀tún yín kúrò, èmi yóò ṣì fi yín ṣe ẹlẹ́yà lójú gbogbo Israẹli.”
3 To whome the Elders of Iabesh said, Giue vs seuen daies respet, that we may sende messengers vnto all the coastes of Israel: and then if no man deliuer vs, we will come out to thee.
Àwọn àgbàgbà Jabesi sì wí fún un pé, “Fún wa ní ọjọ́ méje kí àwa lè rán oníṣẹ́ sí gbogbo Israẹli; àti agbègbè bí ẹni kankan kò bá sì jáde láti gbà wá, àwa yóò fi ara wa fún ọ.”
4 Then came the messengers to Gibeah of Saul, and tolde these tidings in the eares of the people: and all the people lift vp their voices and wept.
Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà sì wá sí Gibeah tí ó jẹ́ ìlú Saulu, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, gbogbo wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún.
5 And behold, Saul came following the cattell out of the fielde, and Saul saide, What aileth this people, that they weepe? And they tolde him the tidings of the men of Iabesh.
Nígbà náà gan an ni Saulu padà wá láti pápá, pẹ̀lú màlúù rẹ̀, ó sì béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn? Èéṣe tí wọ́n fi ń sọkún?” Nígbà náà ni wọ́n tún sọ fún wọn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi.
6 Then the Spirit of God came vpon Saul, when he heard those tidings, and he was exceeding angrie,
Nígbà tí Saulu sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e pẹ̀lú agbára, inú rẹ̀ sì ru sókè.
7 And tooke a yoke of oxen, and hewed them in pieces, and sent them throughout all the coastes of Israel by the hands of messengers, saying, Whosoeuer commeth not foorth after Saul, and after Samuel, so shall his oxen be serued. And the feare of the Lord fell on the people, and they came out with one consent.
Ó sì mú màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì rán ẹyẹẹyọ sí gbogbo Israẹli nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ náà, ó ní i ẹ kéde pé, “Èyí ni a ó ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ Saulu àti Samuẹli lẹ́yìn.” Nígbà náà ni ìbẹ̀rù Olúwa sì mú àwọn ènìyàn, wọ́n sì jáde bí ènìyàn kan ṣoṣo.
8 And when he nombred them in Bezek, the children of Israel were three hundreth thousande men: and the men of Iudah thirtie thousand.
Nígbà tí Saulu sì kó wọn jọ ní Beseki, àwọn ọkùnrin Israẹli tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.
9 Then they saide vnto the messengers that came, So say vnto the men of Iabesh Gilead, To morowe by then the sunne be hote, ye shall haue helpe. And the messengers came and shewed it to the men of Iabesh, which were glad.
Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó wá pé, “Sọ fún àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi pé, ní àkókò tí oòrùn bá mú lọ́la, àwa yóò gbà yín sílẹ̀.” Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà lọ tí wọ́n sì sọ èyí fún àwọn ọkùnrin Jabesi, inú wọn sì dùn.
10 Therefore the men of Iabesh sayde, To morowe we will come out vnto you, and yee shall doe with vs all that pleaseth you.
Wọ́n sọ fún àwọn ará Jabesi pé, “Àwa yóò fi ara wa fún un yín ní ọ̀la, kí ẹ̀yin kí ó ṣe gbogbo èyí tí ó tọ́ lójú yín sí wa.”
11 And when the morowe was come, Saul put the people in three bandes, and they came in vpon the hoste in the morning watche, and slewe the Ammonites vntill the heate of the day: and they that remained, were scattered, so that two of them were not left together.
Ní ọjọ́ kejì Saulu pín àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí ipa mẹ́ta, wọ́n sì ya wọ àgọ́ àwọn ará Ammoni ní ìṣọ́ òwúrọ̀, wọ́n sì pa wọ́n títí di ìmóoru ọjọ́. Àwọn tókù wọ́n sì fọ́nká, tó bẹ́ẹ̀ tí méjì wọn kò kù sí ibìkan.
12 Then the people said vnto Samuel, Who is he that saide, Shall Saul reigne ouer vs? bring those men that we may slaie them.
Àwọn ènìyàn sọ fún Samuẹli pé, “Ta ni ó béèrè wí pé, Saulu yóò ha jẹ ọba lórí wa? Mú àwọn ọkùnrin náà wá, a ó sì pa wọ́n.”
13 But Saul said, There shall no man die this day: for to day the Lord hath saued Israel.
Ṣùgbọ́n Saulu wí pé, “A kì yóò pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí lónìí yìí ni Olúwa ṣiṣẹ́ ìgbàlà ní Israẹli.”
14 Then saide Samuel vnto ye people, Come, that we may goe to Gilgal, and renue the kingdome there.
Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Gilgali, kí a lè fi ẹsẹ̀ Saulu múlẹ̀ bí ọba.”
15 So all the people went to Gilgal, and made Saul King there before the Lord in Gilgal: and there they offered peace offerings before the Lord: and there Saul and all the men of Israel reioyced exceedingly.
Nítorí náà gbogbo ènìyàn lọ sí Gilgali, wọn sí fi Saulu jẹ ọba ní iwájú Olúwa. Níbẹ̀, ni wọn ti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ní iwájú Olúwa, Saulu àti gbogbo Israẹli ṣe àjọyọ̀ ńlá.

< 1 Samuel 11 >