< Psalms 58 >

1 Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́ ẹ̀yin ìjọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́ ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn? 2 Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo, ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé. 3 Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà, lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké. 4 Oró wọn dàbí oró ejò, wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí, 5 tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú, bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó. 6 Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run; ní ẹnu wọn, ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa. 7 Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ; nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́. 8 Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn. 9 Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún; bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ. 10 Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn, nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú. 11 Àwọn ènìyàn yóò wí pé, “Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo; lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”

< Psalms 58 >