< Psalms 21 >

1 Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ, àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!
[For the Chief Musician. A Psalm by David.] The king rejoices in your strength, LORD. How greatly he rejoices in your salvation.
2 Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. (Sela)
You have given him his heart's desire, and have not withheld the request of his lips. (Selah)
3 Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
For you meet him with the blessings of goodness. You set a crown of fine gold on his head.
4 Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un, àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
He asked life of you, you gave it to him, even length of days forever and ever.
5 Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un; ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
His glory is great in your salvation. You lay honor and majesty on him.
6 Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un: ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
For you make him most blessed forever. You make him glad with joy in your presence.
7 Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa; nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà kì yóò sípò padà.
For the king trusts in the LORD. Through the loving kindness of the Most High, he shall not be moved.
8 Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí; ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
Your hand will find out all of your enemies. Your right hand will find all those who hate you.
9 Nígbà tí ìwọ bá yọ ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru. Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀, àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
You will make them as a fiery furnace in the time of your anger. The LORD will swallow them up in his wrath. The fire shall devour them.
10 Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀, àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
You will destroy their descendants from the earth, their posterity from among the descendants of Adam.
11 Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
Though they intend evil against you, devising a wicked scheme, they will not succeed.
12 Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.
For you will make them turn their back, when you aim drawn bows at their face.
13 Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ; a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.
Be exalted, LORD, in your strength, so we will sing and praise your power.

< Psalms 21 >