< Psalms 146 >

1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi. 2 Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi, èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè. 3 Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé, àní, ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́. 4 Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀, ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo. 5 Ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. 6 Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé. 7 Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára, tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa, Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀, 8 Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran, Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga, Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo. 9 Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́. 10 Olúwa jẹ ọba títí láé; Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

< Psalms 146 >