< Psalms 112 >

1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀. 2 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé: ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún. 3 Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀; òdodo rẹ̀ sì dúró láé. 4 Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn: olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo. 5 Ènìyàn rere fi ojúrere hàn, a sì wínni; ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀. 6 Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé: olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé. 7 Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú: ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa. 8 Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á, títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. 9 Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú, nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé; ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá. 10 Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́, yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù: èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

< Psalms 112 >