< Proverbs 18 >

1 Ènìyàn tí kò ba ni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀; ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo. 2 Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí sísọ èrò tirẹ̀. 3 Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé, nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé. 4 Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn, ṣùgbọ́n orísun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń sàn. 5 Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúsàájú fún ènìyàn búburú tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀. 6 Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀ ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba. 7 Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́, ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀. 8 Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn; wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ. 9 Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀ arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun. 10 Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni; olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà. 11 Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn; wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni. 12 Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga, ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá. 13 Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́, èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀. 14 Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn, ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì. 15 Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀; etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀. 16 Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí. 17 Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre, títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo. 18 Ìbò dídì máa ń parí ìjà a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn. 19 Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí ṣòro yípadà ju ìlú olódi lọ, ìjà wọ sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin. 20 Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó; láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó. 21 Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn, àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́. 22 Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere, o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa. 23 Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú, ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra. 24 Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.

< Proverbs 18 >