< Proverbs 16 >

1 Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.
לאדם מערכי-לב ומיהוה מענה לשון
2 Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.
כל-דרכי-איש זך בעיניו ותכן רוחות יהוה
3 Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́, èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.
גל אל-יהוה מעשיך ויכנו מחשבתיך
4 Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́ kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.
כל פעל יהוה למענהו וגם-רשע ליום רעה
5 Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀ mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.
תועבת יהוה כל-גבה-לב יד ליד לא ינקה
6 Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.
בחסד ואמת יכפר עון וביראת יהוה סור מרע
7 Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn, yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà.
ברצות יהוה דרכי-איש גם-אויביו ישלם אתו
8 Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ.
טוב-מעט בצדקה-- מרב תבואות בלא משפט
9 Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.
לב אדם יחשב דרכו ויהוה יכין צעדו
10 Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ sí i ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ ṣèké.
קסם על-שפתי-מלך במשפט לא ימעל-פיו
11 Òdínwọ̀n àti òsùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa; gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.
פלס ומאזני משפט--ליהוה מעשהו כל-אבני-כיס
12 Àwọn ọba kórìíra ìwà àìtọ́ nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.
תועבת מלכים עשות רשע כי בצדקה יכון כסא
13 Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣọ òtítọ́, wọ́n sì fẹ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ òtítọ́.
רצון מלכים שפתי-צדק ודבר ישרים יאהב
14 Ìránṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.
חמת-מלך מלאכי-מות ואיש חכם יכפרנה
15 Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè; ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.
באור-פני-מלך חיים ורצונו כעב מלקוש
16 Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ àti láti yan òye dípò o fàdákà!
קנה-חכמה--מה-טוב מחרוץ וקנות בינה נבחר מכסף
17 Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi, ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.
מסלת ישרים סור מרע שמר נפשו נצר דרכו
18 Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun, agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú.
לפני-שבר גאון ולפני כשלון גבה רוח
19 Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrín àwọn olùpọ́njú jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.
טוב שפל-רוח את-עניים (ענוים) מחלק שלל את-גאים
20 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre, ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
משכיל על-דבר ימצא-טוב ובוטח ביהוה אשריו
21 Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.
לחכם-לב יקרא נבון ומתק שפתים יסיף לקח
22 Òye jẹ́ orísun ìyè fún àwọn tí ó ní i, ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.
מקור חיים שכל בעליו ומוסר אולים אולת
23 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà.
לב חכם ישכיל פיהו ועל-שפתיו יסיף לקח
24 Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.
צוף-דבש אמרי-נעם מתוק לנפש ומרפא לעצם
25 Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.
יש דרך ישר לפני-איש ואחריתה דרכי-מות
26 Ọkàn alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún ara rẹ̀; nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ lọ.
נפש עמל עמלה לו כי-אכף עליו פיהו
27 Ènìyàn búburú ń pète ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.
איש בליעל כרה רעה ועל-שפתיו (שפתו) כאש צרבת
28 Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀ olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà.
איש תהפכות ישלח מדון ונרגן מפריד אלוף
29 Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.
איש חמס יפתה רעהו והוליכו בדרך לא-טוב
30 Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte; ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.
עצה עיניו לחשב תהפכות קרץ שפתיו כלה רעה
31 Adé ògo ni ewú orí jẹ́, ìgbé ayé òdodo ní í mú ni dé bẹ̀.
עטרת תפארת שיבה בדרך צדקה תמצא
32 Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ, ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ.
טוב ארך אפים מגבור ומשל ברוחו מלכד עיר
33 A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ, ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.
בחיק יוטל את-הגורל ומיהוה כל-משפטו

< Proverbs 16 >