< Job 26 >

1 Ṣùgbọ́n Jobu sì dáhùn wí pé, 2 “Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá, báwo ní ìwọ ń ṣe gbe apá ẹni tí kò ní agbára? 3 Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ fun ẹni tí kò ní ọgbọ́n, tàbí báwo òye rẹ to pọ to bẹ́ẹ̀? 4 Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti ẹ̀mí ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?” 5 “Àwọn aláìlágbára ti isà òkú wárìrì, lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. 6 Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run, ibi ìparun kò sí ní ibojì. (Sheol h7585) 7 Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú, ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán. 8 Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn; àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn. 9 Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn, ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí. 10 Ó fi ìdè yí omi òkun ká, títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn. 11 Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì, ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀. 12 Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun; nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́. 13 Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́; ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì. 14 Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀; ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó! Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”

< Job 26 >