< Isaiah 50 >

1 Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà èyí tí mo fi lé e lọ? Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi ni mo tà ọ́ fún? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́; nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ. 2 Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan? Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn? Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́? Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí? Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun, Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀; àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi wọ́n sì kú fún òǹgbẹ. 3 Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀ mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.” 4 Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán, láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró. O jí mi láràárọ̀, o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́. 5 Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí; Èmi kò sì padà sẹ́yìn. 6 Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí, àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi; Èmi kò fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí. 7 Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́, a kì yóò dójútì mí. Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí. 8 Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí. Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí? Jẹ́ kí a kojú ara wa! Ta ni olùfisùn mi? Jẹ́ kí ó kò mí lójú! 9 Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́. Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ; kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run. 10 Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu? Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn tí kò ní ìmọ́lẹ̀, kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín, ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín, àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá. Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá. Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.

< Isaiah 50 >