< Ezekiel 12 >

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
ויהי דבר יהוה אלי לאמר
2 “Ọmọ ènìyàn, ìwọ ń gbé ní àárín ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn. Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́rọ̀ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́rọ̀, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n.
בן אדם בתוך בית המרי אתה ישב אשר עינים להם לראות ולא ראו אזנים להם לשמע ולא שמעו--כי בית מרי הם
3 “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, palẹ̀ ẹrù rẹ mọ́ láti lọ sí ìgbèkùn, ní ọ̀sán gangan ní ojú wọn, kúrò láti ibi tí ìwọ wà lọ sí ibòmíràn. Bóyá bí wọ́n bá rí ọ, wọn yóò sì ronú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.
ואתה בן אדם עשה לך כלי גולה וגלה יומם לעיניהם וגלית ממקומך אל מקום אחר לעיניהם--אולי יראו כי בית מרי המה
4 Di ẹrù ìgbèkùn rẹ lójú wọn ní ọ̀sán án gangan, nígbà tí ó bá sì di alẹ́, ní ojú wọn, máa lọ sí ìgbèkùn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó lọ ìgbèkùn ṣe máa ń ṣe.
והוצאת כליך ככלי גולה יומם--לעיניהם ואתה תצא בערב לעיניהם כמוצאי גולה
5 Dá ògiri lu ní ojú wọn, kí ìwọ sì gba ibẹ̀ kó ẹrù rẹ jáde.
לעיניהם חתר לך בקיר והוצאת בו
6 Gbé ẹrù rẹ lé èjìká ní ojú wọn, bo ojú rẹ, kí ìwọ má ba à rí ilẹ̀, sì ru ẹrù rẹ lọ ní alẹ́ nítorí pé mo fi ọ́ ṣe àmì fún ilé Israẹli.”
לעיניהם על כתף תשא בעלטה תוציא--פניך תכסה ולא תראה את הארץ כי מופת נתתיך לבית ישראל
7 Mo ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi. Mo kó ẹrù mi jáde ní ọ̀sán án láti lọ fun ìgbèkùn. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, mo dá ògiri lu pẹ̀lú ọwọ́ mi. Mo sì gbe ẹrù mi lé èjìká nínú òkùnkùn ní ojú wọn.
ואעש כן כאשר צויתי כלי הוצאתי ככלי גולה יומם ובערב חתרתי לי בקיר ביד בעלטה הוצאתי על כתף נשאתי לעיניהם
8 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
ויהי דבר יהוה אלי בבקר לאמר
9 “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé Israẹli tilẹ̀ bi ọ́ pé, ‘Kí ni ohun tí o ń ṣe túmọ̀ sí?’
בן אדם הלא אמרו אליך בית ישראל בית המרי מה אתה עשה
10 “Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ yìí kan àwọn ọmọ-aládé Jerusalẹmu àti gbogbo ilé Israẹli tí ó wà ní àárín rẹ.
אמר אליהם כה אמר אדני יהוה הנשיא המשא הזה בירושלם וכל בית ישראל אשר המה בתוכם
11 Sọ fún wọn pé, Èmi jẹ́ àmì fún yín’. “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí wọn. Wọn ó kó lọ sí ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí ẹni ti a dè ní ìgbèkùn.
אמר אני מופתכם כאשר עשיתי כן יעשה להם--בגולה בשבי ילכו
12 “Ọmọ-aládé tí ó wà ní àárín wọn yóò di ẹrù rẹ̀ lé èjìká ní alẹ́ yóò sì jáde lọ, òun náà yóò da ògiri lu kí ó le gba ibẹ̀ jáde. Yóò sì bo ojú rẹ̀ kí ó má ba à rí ilẹ̀.
והנשיא אשר בתוכם אל כתף ישא בעלטה ויצא--בקיר יחתרו להוציא בו פניו יכסה--יען אשר לא יראה לעין הוא את הארץ
13 Èmi yóò ta àwọ̀n mi lé e lórí, yóò sì kó sínú okùn, Èmi yóò sì mú lọ sí Babeli, ní ilẹ̀ Kaldea, ṣùgbọ́n kò ní fojúrí ilẹ̀ náà ibẹ̀ ni yóò kú sí.
ופרשתי את רשתי עליו ונתפש במצודתי והבאתי אתו בבלה ארץ כשדים ואותה לא יראה ושם ימות
14 Gbogbo àwọn tó yí i ká láti ràn án lọ́wọ́ ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ni Èmi yóò túká sí afẹ́fẹ́, èmi yóò sì tún fi idà lé wọn kiri.
וכל אשר סביבתיו עזרה וכל אגפיו אזרה לכל רוח וחרב אריק אחריהם
15 “Wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa nígbà tí mo bá tú wọn ká ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ káàkiri.
וידעו כי אני יהוה בהפיצי אותם בגוים וזריתי אותם בארצות
16 Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ díẹ̀ kù lára wọn, ní ọwọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, kí wọn le jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe ìríra wọn ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè yìí. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.”
והותרתי מהם אנשי מספר מחרב מרעב ומדבר--למען יספרו את כל תועבותיהם בגוים אשר באו שם וידעו כי אני יהוה
17 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
ויהי דבר יהוה אלי לאמר
18 “Ọmọ ènìyàn, jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ìwárìrì, sì mu omi rẹ pẹ̀lú ìwárìrì àti àìbalẹ̀ àyà.
בן אדם לחמך ברעש תאכל ומימיך ברגזה ובדאגה תשתה
19 Sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti ilẹ̀ Israẹli pé, pẹ̀lú àìbalẹ̀ àyà ni wọn yóò máa jẹun wọn, wọn yóò sì mu omi pẹ̀lú àìnírètí, kí ilẹ̀ wọn lè di ahoro torí ìwà ipá àwọn tó ń gbé ibẹ̀.
ואמרת אל עם הארץ כה אמר אדני יהוה ליושבי ירושלם אל אדמת ישראל לחמם בדאגה יאכלו ומימיהם בשממון ישתו--למען תשם ארצה ממלאה מחמס כל הישבים בה
20 Ìlú tó jẹ́ ibùgbé ènìyàn tẹ́lẹ̀ yóò di òfo, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’”
והערים הנושבות תחרבנה והארץ שממה תהיה וידעתם כי אני יהוה
21 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:
ויהי דבר יהוה אלי לאמר
22 “Ọmọ ènìyàn, irú òwe wo ni ẹ pa nílẹ̀ Israẹli pé: ‘A fa ọjọ́ gùn, gbogbo ìran di asán’?
בן אדם מה המשל הזה לכם על אדמת ישראל לאמר יארכו הימים ואבד כל חזון
23 Nítorí náà wí fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, Èmi yóò fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní ipa mọ́ ní Israẹli.’ Sọ fún wọn, ‘Ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí nígbà tí gbogbo ìran àti ìsọtẹ́lẹ̀ yóò sì wá sí ìmúṣẹ.
לכן אמר אליהם כה אמר אדני יהוה השבתי את המשל הזה ולא ימשלו אתו עוד בישראל כי אם דבר אליהם קרבו הימים ודבר כל חזון
24 Nítorí kò ní sí ìran asán tàbí àfọ̀ṣẹ tí ó ń pọ́n ni mọ́ ní àárín ilé Israẹli.
כי לא יהיה עוד כל חזון שוא--ומקסם חלק בתוך בית ישראל
25 Ṣùgbọ́n, Èmi Olúwa yóò sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò sì ṣẹ láì falẹ̀. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ní àsìkò yín, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀ ilé ni Èmi yóò mú ọ̀rọ̀ yówù tí mo bá sọ ṣẹ.’”
כי אני יהוה אדבר את אשר אדבר דבר ויעשה--לא תמשך עוד כי בימיכם בית המרי אדבר דבר ועשיתיו נאם אדני יהוה
26 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:
ויהי דבר יהוה אלי לאמר
27 “Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ń wí pé, ‘Ìran ọjọ́ pípẹ́ ni ìwọ rí, ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ nípa àsìkò tó jìnnà réré.’
בן אדם הנה בית ישראל אמרים החזון אשר הוא חזה לימים רבים ולעתים רחוקות הוא נבא
28 “Nítorí náà sọ fún wọn, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, kò sí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ mi tí yóò sún síwájú mọ́; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí mo bá sọ yóò ṣẹ.’”
לכן אמר אליהם כה אמר אדני יהוה לא תמשך עוד כל דברי--אשר אדבר דבר ויעשה נאם אדני יהוה

< Ezekiel 12 >