< مزامیر 24 >

مزمور داود زمین و پری آن از آن خداوند است. ربع مسکون و ساکنان آن. ۱ 1
Ti Dafidi. Saamu. Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
زیرا که اواساس آن را بر دریاها نهاد. و آن را بر نهرها ثابت گردانید. ۲ 2
nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkun ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.
کیست که به کوه خداوند برآید؟ وکیست که به مکان قدس او ساکن شود؟ ۳ 3
Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ? Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
او که پاک دست و صاف دل باشد، که جان خود را به بطالت ندهد و قسم دروغ نخورد. ۴ 4
Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké.
او برکت را ازخداوند خواهد یافت. و عدالت را از خدای نجات خود. ۵ 5
Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa, àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
این است طبقه طالبان او. طالبان روی تو‌ای (خدای ) یعقوب. سلاه. ۶ 6
Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. (Sela)
‌ای دروازه‌ها سرهای خود را برافرازید! ای درهای ابدی برافراشته شوید تا پادشاه جلال داخل شود! ۷ 7
Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà; kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé.
این پادشاه جلال کیست؟ خداوندقدیر و جبار؟ خداوند که در جنگ جبار است. ۸ 8
Ta ni ọba ògo náà? Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le, Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
‌ای دروازه‌ها، سرهای خود را برافرازید! ای درهای ابدی برافرازید تا پادشاه جلال داخل شود! ۹ 9
Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà; kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo le è wọlé wá.
این پادشاه جلال کیست؟ یهوه صبایوت پادشاه جلال اوست. سلاه. ۱۰ 10
Ta ni Ọba ògo náà? Olúwa àwọn ọmọ-ogun Òun ni Ọba ògo náà. (Sela)

< مزامیر 24 >