< Ephesians 3 >

1 For this cause I, Paul, am the prisoner of Christ Jesus on behalf of you Gentiles,
Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà.
2 if it is so that you have heard of the administration of that grace of God which was given me toward you,
Lóòtítọ́ ẹ̀yin tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fi fún mi fún yín;
3 how that by revelation the mystery was made known to me, as I wrote before in few words,
bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni ṣókí.
4 by which, when you read, you can perceive my understanding in the mystery of Christ,
Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kristi.
5 which in other generations was not made known to the children of men, as it has now been revealed to his holy apostles and prophets in the Spirit,
Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí;
6 that the Gentiles are fellow heirs and fellow members of the body, and fellow partakers of his promise in Christ Jesus through the Good News,
pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kristi Jesu nípa ìyìnrere.
7 of which I was made a servant according to the gift of that grace of God which was given me according to the working of his power.
Ìránṣẹ́ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.
8 To me, the very least of all saints, was this grace given, to preach to the Gentiles the unsearchable riches of Christ,
Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà;
9 and to make all men see what is the administration of the mystery which for ages (aiōn g165) has been hidden in God, who created all things through Jesus Christ,
àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi. (aiōn g165)
10 to the intent that now through the assembly the manifold wisdom of God might be made known to the principalities and the powers in the heavenly places,
Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ,
11 according to the purpose of the ages (aiōn g165) which he accomplished in Christ Jesus our Lord.
gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ayérayé tí ó ti pinnu nínú Kristi Jesu Olúwa wa. (aiōn g165)
12 In him we have boldness and access in confidence through our faith in him.
Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.
13 Therefore I ask that you may not lose heart at my troubles for you, which are your glory.
Nítorí náà, mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, èyí tí ṣe ògo yín.
14 For this cause, I bow my knees to the Father of our Lord Jesus Christ,
Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi.
15 from whom every family in heaven and on earth is named,
Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé.
16 that he would grant you, according to the riches of his glory, that you may be strengthened with power through his Spirit in the inner person,
Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.
17 that Christ may dwell in your hearts through faith, to the end that you, being rooted and grounded in love,
Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́;
18 may be strengthened to comprehend with all the saints what is the width and length and height and depth,
kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́.
19 and to know Christ’s love which surpasses knowledge, that you may be filled with all the fullness of God.
Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín.
20 Now to him who is able to do exceedingly abundantly above all that we ask or think, according to the power that works in us,
Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa.
21 to him be the glory in the assembly and in Christ Jesus to all generations for the age (aiōn g165) of the ages (aiōn g165). Amen.
Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín. (aiōn g165)

< Ephesians 3 >