< 2 Mosebog 24 >

1 Og han sagde til Moses: "Stig op til HERREN, du og Aron, Nadab og Abih og halvfjerdsindstyve af Israels Ældste, og tilbed i Frastand;
Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Gòkè tọ Olúwa wá, ìwọ àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré.
2 Moses alene skal træde hen til HERREN, de andre ikke, og det øvrige Folk må ikke følge med ham derop."
Ṣùgbọ́n Mose nìkan ṣoṣo ni yóò súnmọ́ Olúwa; àwọn tókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò gbọdọ̀ gòkè wá pẹ̀lú rẹ̀.”
3 Derpå kom Moses og kundgjorde hele Folket alle HERRENs Ord og alle Lovbudene, og hele Folket svarede enstemmigt: "Alle de Ord, HERREN har talet, vil vi overholde."
Nígbà ti Mose lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin Olúwa, wọ́n wí ní ohùn kan pé, “Gbogbo ohun ti Olúwa wí ni àwa yóò ṣe.”
4 Da skrev Moses alle HERRENs Ord op; og tidligt næste Morgen rejste han ved Foden af Bjerget et Alter og tolv Stenstøtter svarende til Israels tolv Stammer.
Nígbà náà ni Mose kọ gbogbo ohun tí Olúwa sọ sílẹ̀. Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà. Ó ṣe ọ̀wọ́n òkúta méjìlá. Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.
5 Derefter sendte han de unge Mænd blandt Israeliterne hen for at bringe Brændofre og slagte unge Tyre som Takofre til HERREN.
Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si Olúwa.
6 Og Moses tog den ene Halvdel af Blodet og gød det i Offerskålene, men den anden Halvdel sprængte han på Alteret.
Mose bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ.
7 Så tog han Pagtsbogen og læste den op i Folkets Påhør, og de sagde: "Vi vil gøre alt, hvad HERREN har talet, og lyde ham!"
Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí. Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.”
8 Derpå tog Moses Blodet og sprængte det på Folket, idet han sagde: "Se, dette er Pagtens Blod, den Pagt, HERREN har sluttet med eder på Grundlag af alle disse Ord."
Nígbà náà ni Mose gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Olúwa ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”
9 Og Moses, Aron, Nadab og Abihu og halvfjerdsindstyve af Israels Ældste steg op
Mose àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli gòkè lọ.
10 og skuede Israels Gud; under hans Fødder var der ligesom Safirfliser, som selve Himmelen i Stråleglans.
Wọ́n sì rí Ọlọ́run Israẹli. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta safire ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ nigínnigín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnra rẹ̀.
11 Men han lagde ikke Hånd på Israeliternes ypperste Mænd. De skuede Gud, og de spiste og drak.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn àgbàgbà Israẹli wọ̀nyí; wọ́n ri Ọlọ́run, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.
12 Og HERREN sagde til Moses: "Stig op til mig på Bjerget og bliv der, så vil jeg give dig Stentavlerne, Loven og Budet, som jeg har opskrevet til Vejledning for dem."
Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhìn-ín. Èmi yóò sì fún ọ ní wàláà òkúta pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn.”
13 Da bød Moses og Josua, hans Medhjælper op, og Moses steg op på Guds Bjerg;
Nígbà náà ni Mose jáde lọ pẹ̀lú Joṣua arákùnrin rẹ̀. Mose lọ sí orí òkè Ọlọ́run.
14 men til de Ældste sagde han: "Vent på os her, til vi kommer tilbage til eder. Se, Aron og Hur er hos eder; er der nogen, der har en Retstrætte, kan han henvende sig til dem!"
Ó sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsi i, Aaroni àti Huri ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnìkan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.”
15 Derpå steg Moses op på Bjerget. Da indhyllede Skyen Bjerget,
Nígbà tí Mose gun orí òkè lọ, ìkùùkuu bo orí òkè náà.
16 og HERRENs Herlighed nedlod sig på Sinaj Bjerg. Og Skyen indhyllede Sinaj Bjerg i seks Dage, men den syvende Dag råbte HERREN ud fra Skyen til Moses;
Ògo Olúwa sì wà ní orí òkè Sinai. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni Olúwa kọ sí Mose láti inú ìkùùkuu náà wá.
17 og medens HERRENs Herlighed viste sig for Israeliternes Øjne som en fortærende Ild på Bjergets Top,
Ni ojú àwọn ọmọ Israẹli ògo Olúwa náà dàbí iná ajónirun ni orí òkè.
18 gik Moses ind i Skyen og steg op på Bjerget. Og Moses blev på Bjerget i fyrretyve Dage og fyrretyve Nætter.
Nígbà náà ni Mose wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.

< 2 Mosebog 24 >